Iyiola Oyedepo: Ọgọrọ ọmọ ẹgbẹ PDP ni yoo dárapọ mọ APC ní Kwara

AWORAN AKOGUN OYEDEPO Image copyright @akoguniyiola
Àkọlé àwòrán Oyedepo ni oun ko le ba Saraki sepọ ninu ẹgbẹ PDP

Awọn eekan ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party PDP ni ipinlẹ Kwara ti fi ẹgbẹ silẹ lati darapomo ẹgbẹ oselu All Progressives Congress,APC.

Igbesẹ yi n waye gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ APC naa se n kọwọrin kuro ninu ẹgbẹ wọn lo si PDP.

Iroyin to tẹwa lọwọ so pe Alaga ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Kwara Ogbẹni Iyiola Oyedepo wa lara awọn to kọkọ kede pe awọn yoo kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ si APC.

Nigba ti o n soro lori eto ori redio kan ni ilu Ilorin, Iyiola ni oun ko le ba Aarẹ ile asofin agba Bukola Saraki sisẹ papọ.

''O tẹmi lọrun kin darapomọ APC ju kin ba Saraki sisẹ. Ni kete ti mo ba ti pari lori eto yi ni mo ma gba ọna Abuja lọ lati kowe fẹgbẹ silẹ''

Oun nikan kọ ni o kuro ninu PDP lọ si APC.

Ni Ọjọru ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan se iwọde nilu Ilorin lati fi ẹhonu han pẹ awọn ko si ninu ẹgbẹ mo.

Ọjọgbọn Shuaib Oba Adulraheem to fi igba kan jẹ ọga agba ile ẹko fasiti Ilorin, toun naa si n gbero lati jẹ Gomina ipinle Kwara kuro ninu ẹgbẹ PDP.

Image copyright Talba Offa Chapter
Àkọlé àwòrán Awọn to n mu ara ilu Kwara sin lo fe pada si PDP, a ko le bawọn se pọ

Ninu ifọrọwanilẹnuwọ pẹlu ile isẹ BBC, o ni PDP ti 'fori sanpọn ni ipinlẹ Kwara'

Egbẹ naa ti di atan bayi. Imotara ẹni nikan lo ku ninu ẹgbẹ naa loni.

O ni awọn duro sinu ẹgbe naa nitori pẹ awọn amunisin kuro nibẹ la ti lo si APC, sugbọn ni bayi ti wọn ti pada de, ko si sise ko si aise ju pe ki a fi ẹgbẹ silẹ fun wọn.

Asofin mẹtalelogun naa kuro legbẹ APC

Loni oloni naa ni agbo pe awọn asofin mẹtalelogun ni ile asofin ipinlẹ Kwara kọwọrin pẹlu olori ile asofin kuro ninu APC lọ si PDP.

Eeeyan kan soso ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ni ko kuro.

Ali Ahmad to jẹ olori ile so ni oju opo Twitter re pẹ ni ọdun 2014 ti oun fi PDP silẹ lo si APC, nise ni inu oun bajẹ sugbọn loni ti oun pada,ayo oun kun.