Aarẹ Buhari n lọ sinmi ni London fun ọjọ mẹwa

Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ wí pé ní àìsí nílé òun, igbákejì rẹ̀ ni yó máa delé dè é.

Agbẹnusọ aarẹ ti sọ ọ́ lójú òpó Twitter pé igbakeji aarẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Oṣinbajo ni yóò máa sisẹ́ ààrẹ fún àsìkò tí ààrẹ fi lọ sinmi ni Ilẹ Gẹẹsi.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lo ti lọ si Ilẹ Gẹẹsi ni London lati lọ lo isinmi ọlọjọ mẹwaa, eleyi ti yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kẹta, Osu Kẹjọ ti a wa yii.

Agbẹnusọ aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu to fi eyi lede ni ori ẹrọ ikansiraẹni Twitter rẹ, sọ wi pe ọjọ mẹwa ni Buhari yoo lo lati lọ se ayẹwo ara rẹ.

Shehu ni aarẹ Buhari ni asẹ ati ẹtọ ni abẹ ofin ilẹ Naijiria ti ọdun 1999, labẹ ẹka 145 (1), lati lọ fun isinmi ati ayẹwo ara rẹ, atiwipe awọn ti fi iwe ransẹ si Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Agbẹnusọ Ile ati Ile Asojusofin.

Agbẹnusọ aarẹ ti sọ ọ́ lójú òpó Twitter pé igbakeji aarẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Oṣinbajo ni yóò máa sisẹ́ ààrẹ fún àsìkò tí ààrẹ fi lọ sinmi ni Ilẹ Gẹẹsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlóṣelú máa ń wá ẹgbẹ́ ti wọn lè lò láti mu ìpinu wọn ṣẹ

Ti a ko ba gbagbe, Osu Kẹsan, ọdun to kọja ni Aarẹ Buhari lọ irinajo si ilẹ Gẹẹsi lati lọ se ayẹwo ara rẹ.