FEC: ìjọba buwọlu pàsípàrọ̀ ẹlẹ́wọn láti China

Image copyright Government of Nig/twitter
Àkọlé àwòrán gbìmọ̀ aláṣẹ nínú ìpàdé kan náà tí búwọlu ìgbésẹ̀ amúṣẹ́ṣe lóri dídẹ́kun kíkówó ìlú lọ sí ilẹ̀ òkèrè

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba ti fàṣẹ sí ìpààrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọn pẹ̀lú ìjọba China láti dá awọn ẹlẹ́wọn pade lati wá parí ẹ̀wọ̀n wọn ní Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Irú ẹ̀dá wo ni Bukọla Saraki jẹ́ ?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒní ni ìrántí ọjọ́ tí Fẹla papòdà
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlóṣelú máa ń wá ẹgbẹ́ ti wọn lè lò láti mu ìpinu wọn ṣẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn Obinrin Dahomey: Awọn obinrin ilẹ Afirika ti wọn yii itan pada re e

Mínísítà fún ìdájọ́, Abubakar Malami ló ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ ọ̀hún léyìn ìpàdé ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ìgbìmọ̀ àláṣẹ èyí ti ààrẹ Muhammadu Buhari nílùú Abuja.

Ó sàlàyé pé lára àwọn ọmọ Nàìjíríà tọ́rọ̀ náà kan níbàyìí ní àwọn ti wọn wà ní ọgbà ẹwọn Macau, ẹkun ìwọ̀orun kan ní orílẹ̀èdè China.

Mínísítà sọ pé kí ètò náà tó fìdí múlẹ̀, ó nílò láti gba ìfọwọ́sí láti ọ̀dọ̀ ìjọba China bí ìjọba náà ṣe tún ń pinu irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀èdè mìíran.

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ nínú ìpàdé kan náà, tí búwọlu ìgbésẹ̀ amúṣẹ́ṣe lóri dídẹ́kun kíkówó ìlú lọ sí ilẹ̀ òkèrè àti gbígbogun ti lílu owó ìlú ní póńpó.