Bukola Saraki: Kí ló dé tí Adams Oshiomole n fẹ́ kó gbé adé APC sílẹ̀?

Oshiomole àti Buhari Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán Alága ẹgbẹ́ APC, Adams Oshiomole ní kí Saraki ṣe ohun tó yẹ́ nípa fífí ipò sílẹ

"Ko yẹ ki o gbe ade ti wọn fi de ọ lori ninu ile kan lọ sí ilé ẹlomiran.''

Alaga apapọ f'ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Adams Oshiomole lo sọ bẹẹ lati fi sapejuwe kikuro ti Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ si Peoples Democratic Party, PDP.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Osu kẹrin lẹyin ti Aarẹ Buhari gbe aba eto isuna ọdun 2018 kalẹ, ko tii lojuutu niwaju awọn asofin apapọ

O sọ ọ̀rọ̀ naa lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ipade l'Ọ́jọ́rú, pẹlu awọn gomina to kù sinu ẹgbẹ oṣelu APC.

Oshiomole ni ohun to kan fun Saraki lẹyin to fi ẹgbẹ awọn silẹ ni lati fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Aarẹ ile aṣofin.

Irú ẹ̀dá wo ni Bukọla Saraki jẹ́ ?

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ni Saraki kede pe oun ti kuro ni APC lọ si ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP.

Image copyright Presidency

Lẹyin to ṣe bẹ ẹ ni awọn eniyan nlanla lagbo oṣelu naa fi ẹgbẹ naa silẹ - Lara wọn ni akọwe ikede fun APC, Bolaji Abdullahi, ati gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, ati awọn mi i.

Oshiomole ni kikuro ti awọn eniyan naa kuro ninu ẹgbẹ awọn ko ba awọn ni ojiji, nitori pe awọn ti n foju sọna fun un.

Amọ o ni, o yẹ ki Saraki ṣe ohun to yẹ, nipa fi fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi aarẹ ile aṣofin.

Oshiomole nkan ko le fi bẹ ẹ r'ọrun fun APC nitori awọn to fi ẹgbẹ silẹ, o ni sṣugbọn, ẹni kan, ibo kan ni yoo bori lọjọ idibo.