Zimbabwe Election: Ẹgbẹ́ alátakò kọ èsì ìdìbò

Emmerson Mnangagwa ààrẹ Zimbabwe
Àkọlé àwòrán Ìdá ààdọta o lé ní Mnangagwa fí tayo alátakò rẹ̀ níbí ìdìbo náà

Ààrẹ Emmerson Mnangagwa ti jáwé olúborí níbí ìdìbò sípò ààrẹ orílẹ̀èdè Zimbabwe.

Àjọ elétò ìdìbò Zimbabwe sàlàyé pé nínú àwọn ẹkùn mẹ́wàá, Mnangagwa jáwé olúborí nínú ìdá ààdọ́ta ó lé tí adarí ẹgbẹ́ alátakò rẹ̀ Nelson Chamisa sí ní ìdá ogójì àti díẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Olùdíje gbé APC lọ sílé ẹjọ́ nítorí èsì ìbò

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá ìbarùn-ún: Mo rò pé ‘scan’ ń pa irọ́ niní oyún pé márùn-ún ni màá bí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒní ni ìrántí ọjọ́ tí Fẹla papòdà

Mnangagwa tó wá láti inú ẹgbẹ́ òṣèluú Zanu-PF, gbàjọba gẹ́gẹ́ bí ààrẹ nínú oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá lọ́wọ́ Robert Mugabe.

Nínú ọ̀rọ̀ Mnangagwa tó fí ṣọwọ lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀, o ní ìjáwé olúborí òhun jẹ́ kí òhun tí ní ìrẹ̀lẹ̀ síì

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú MDC sọ pé kò sí àrídájú ìbò ti wọn kà nítorí ọlọ́pàá ló wá gbé ọ̀pọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ alátakò kúro níbi tí àwọn elétò ìdìbò tí ń ka ìbò

léyìn èyí ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò gba ìgboro Harare lati fẹ̀honú han pé màgòmágò wáyé nínú ìdìbò náà, tí ènìyàn mẹ́fà sì ti gbé ẹ̀mi mì.

Àkọlé àwòrán Ìdìbò yíì ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe lò láti mú àláfìà padà bọ̀ sípò ní orílẹ̀-èdè náà

Ìdìbò yìí ní àkọ́kọ́ lẹ́yìntí wọn yọ Mugabe ẹni ọmọ ọdún márùn-ùn lé láàdọ́rùn kúrò nípò ààrẹ lọ́dún tó kọjá.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ìdìbò yìí ní alákọ̀ọ́kọ́ láti ìgbà tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí, Robert Mugabe ti kúrò lórí oyè ní ọdún tó kójá.

Ènìyàn mẹ́ta ti kú ní ìdìbò Zimbabwe

Ijọba ilẹ Zimbabwe ti ti awọn ilẹ itaja gbogbo to wa ni olu-ilu orilẹede Zimbabwe, Harare lẹyin ti ija bẹ ẹ lẹ nigba ti awọn eniyan n reti esi idibo si ipo aarẹ lorilẹede naa.

Awọn oloogun pẹlu ibọn wọn ni wọn n kaakiri agbeegbe naa pẹlu ikilọ pe ki olukaluku so ewe agbejẹ mọ ọwọ titi esi idibo yoo fi jade.

Eniyan mẹta ni o padanu ẹmi wọn ni Ọjọru lasiko ti ija bẹẹẹ laarin awọn ẹsọ alaabo ati awọn alatilẹyin fun adari ẹgbẹ alatako, Nelson Chamisa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒní ni ìrántí ọjọ́ tí Fẹla papòdà

Awọn ẹgbẹ alatako sọ wi pe wọn se magomago ninu idibo to waye ni Ọjọ Aje lati ri wi pe Aarẹ Emmerson Mnangagwa wọle gẹgẹbi aarẹ ti wọn di ibo yan.

Idibo ti wọn reti esi rẹ yii ni alakọkọ lati igba ti Aarẹ tẹlẹri, Robert Mugabe ti kuro lori oye ni ọdun to kọja.

Related Topics