Ọdunlade Adekọla gbóṣùbà f'áwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ilé

Ọdunlade Adekọla gbóṣùbà f'áwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ilé

Gbajugbaja elere tiata Yollywood ni, Ọdunlade Adekọla, ti gboriyin fun awọn ọkunrin to mọ iṣẹ́ ilé ṣe daadaa.

Ọdunlade Adekọla ni ohun idunnu ni fun oun lati ran iyawo oun lọwọ ninu ile.

Gbajugbaja oṣere Yollywood naa sọ eyi di mimọ ninu fidio kan to fi si oju opo instagram rẹ ni ọjọ Abamẹta nibi to ti n fọṣọ nile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Riran iyawo mi lọwọ jẹ ohun idunnu fun mi ni gbogbo igba. Ẹnikeji mi ni. Mo fun un ni idaniloju ifẹ mi nigba ti mo ba ti n ran an lọwọ lori awọn iṣẹ ile.

Mo gboṣuba fun gbogbo awọn ọkunrin to n ran awọn aya wọn lọwọ. #Assurancetemi

Ọ̀dunlade Adekọla ti pupọ ololufẹ rẹ mọ si ọmọga farahan ninu fidio naa ninu eyi ti o ti n fọ aṣọ obinrin eyi to fi n tọka si aṣọ iyawo rẹ.