2019 Election: Ilé Asófin késí INEC láti fi N143bn sọwọ́ sí wọn lẹ́ẹ̀kan si

Saraki atawọn aṣofin apapọ Image copyright Senate Nigeria
Àkọlé àwòrán Ọjọ karundinlọgbọn Oṣu Kẹsan ni awọn aṣofin agba yoo pada si ẹnu iṣẹ

Ariyanjiyan su yọ laarin ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ati Igbimo to n bojuto ọrọ eto idibo ni Ile Igbimo Asofin.

Igbimọ naa faake kọri wi pe awọn ko ni bu owo lu eto isuna toto biliọnu mọkandinlaadọwa ti wọn gbe wa si waju wọn, ayafi ti wọn ba gbe iye eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari koko gbe ka iwaju wọn ni alakọkọ.

Ile Igbimọ Asofin Agba ti kesi ajọ INEC lati pada gbe aba iṣuna oni billiọnu mẹtalelogoje (N143bn ) to wọn nilo fun eto idibo gbogboogbo ni ọdun 2019 wa siwaju oun.

Igbimọ apapọ ti Ile Igbimọ Asofin lori ajọ INEC ti Sẹnetọ Suleiman Nazif jẹ adari fun, lo paṣẹ bẹ lẹyin ipade to ṣe l'ọjọ Aje ọ̀ṣẹ̀ yii, ti wọn si fi ikede rẹ sita lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter.

Igbimọ naa f'ẹnuko pe Inec gbọdọ tun àbá owo isuna ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi sọ wọ si wọn pada wa ni ẹẹkan si, ki awọn le wo o finifini.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Ọjọ keje, Oṣu Kẹjọ, 2018, lo yẹ ki awọn aṣofin naa kọkọ ṣe ipade pajawiri ti Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki pe, lori owo eto iṣuna ajọ INEC ati 'ilọsiwaju Naijiria'.

Sugbọn, ipade naa ko le waye nitori 'wahala kan' to waye nile aṣofin naa ni ọjọ ipade.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Lẹ́yìn wàhálà tó wáyé nílé aṣòfin ni Bukọla Saraki ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn oníròyìn àgbáye

Eyi ri bẹẹ nitori wahala to waye nile aṣofin naa ni owurọ kutu-kutu ọjọ ipade, pẹlu bi awọn aṣofin kan ti ko ṣe ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe fẹsun kan pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo DSS di ọna mọ wọn lati wọn ile aṣofin.

Image copyright kwange
Àkọlé àwòrán Asòfin yóò ṣe ìpàdé pàjáwìrì l'Abuja

Èso wo ni àìpadà àwọn sílé àwọn aṣòfin lé bí?

  • Owo tijọba apapọ fẹ ẹ ya latilẹ okeere ko ni i ṣe e ya.
  • Lai si ibuwọlu awọn aṣofin, ko si ọna ti owo yoo fi jade sita fun ajọ INEC lati bẹrẹ igbaradi fun eto idibo 2019.
  • Bakan naa ni iwadii awọn iyansipo lawọn ajọ ati ileeṣẹ ijọba bii EFCC, ICPC, igbakeji banki apapọ orilẹ-ede Naijiria atawọn ipo miran ko ni i ṣeeṣe.

Eyi si ti mu ki awọn onimọ nipa ohun to n lọ ni Naijiria, sọ pe eyi le ṣe akoba fun eto idibo gbogboogbo naa.

Iléèṣẹ́ Ààrẹ bẹ àwọn aṣòfin láti bẹ̀rẹ̀ ìjókò padà

Ṣaaju ki Saraki to pe ipade pajawiri naa ni ileeṣẹ aarẹ bẹ àwọn aṣofin pe ki wọ́n bẹrẹ ijoko ilé ìgbìmọ̀ padà laipẹ nitori ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.

Sẹnetọ Ita Enang, to jẹ olubadamọran fun aarẹ Buhari lori ọrọ ile aṣofin apapọ, lo fi ẹ̀bẹ̀ naa sita.

Oriṣii nkan ni àwọn eeyan gba pe o n jẹ kile iṣẹ aarẹ maa parọwa fun àwọn ọmọ ilé igbimọ lasiko yii bíi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adelé Ààrẹ, Yẹmi Ọṣinbajo gba ìṣẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá àjọ DSS, Lawal Daura nítorí wàhálà tó wáyé nílé aṣòfin

Ẹwẹ, ohun kan ti isinmi wọn yii tun ṣeeṣe ko ṣe akoba fun ni eto ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria, nitori pe igbesẹ pinpin owo lati ẹka ijọba kan si mi i ko ni ṣeeṣe lai si aṣẹ awọn aṣofin, eyi ti yoo ran awọn ẹka eto ọrọ aje yooku lọwọ.

Njẹ ẹgbẹ APC mọ nipa wahala naa gẹgẹ bi ẹsun ti PDP fi kan an?

Adele akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC, Ọgbẹni Yekini Nabena, ninu ikede kan to fi sita ni irọ patapata ni pe alaga apapọ fun ẹgbẹ APC, Adams Oshiomole lo wa ni idi rogbodiyan to waye naa.

O ni aarin awọn aṣofin naa ni ki wọn o ti wadi bi wahala naa ṣe waye. Ati pe ẹgbẹ APC naa ṣi n woye bi nkan ṣe nlọ nile aṣofin.

Awọn sẹnetọ PDP fẹ̀sùn kan APC pe wọn fẹ yọ Saraki l'óyè

Awọn sẹnetọ kan ninu ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, ni gbogbo iṣẹlẹ to waye nile igbimọ aṣofin jẹ ọna lati mu ki awọn ọgbọn sẹnetọ to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC yọ aarẹ ile asọfin agba.

Ṣugbọn oluranlọwọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ ile aṣofin, Ita Enang, sọ pe 'Aarẹ Buhari ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.'

Díẹ̀ lára àwọn nkan tí àwọn aṣòfin fi síta lójú òpó Twitter nìyíì:

Ọkan nínú àwọn sẹ́natọ Rafiu Ibrahim ní 'wọn dí òun l'ọ́nà láti wọ ilé ìgbìmọ̀.'

Àwọn míran ní ìdìtẹ̀ láti yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ Bukola Saraki àti Ike Ìkweremadu ìgbákejì rẹ̀ nípò.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje ni ile aṣofin agba gunle isinmi ẹnu iṣẹ, lẹyin ti awọn aṣofin kan fi ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, silẹ lati darapọ mọ APC.

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ni awọn aṣofin agba pinnu lati pada si ẹnu iṣẹ.

"Ohun tí ojú opó ń rí láwùjọ kò kéré"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌbìnrin tó fẹ́ ṣojú àwọn ẹ̀yà Sheedi