Fayose: Dídarapọ̀ mọ́ APC dàbí bíbá adigunjàlè ṣ'ọ̀rẹ́ ni

Fayose Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Fayose jẹ alatako ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress

'Irọ́ ni pé èmi àti Oluṣọla Ẹlẹka wa Tinubu lọ'

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti ni ko si ootọ kankan ninu iroyin to gba igboro pe, oun ni nkan 'ṣe pẹlu Asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Tinubu.

Saaju ni aworan kan gba ori ẹrọ ayelujara, pe Gomina Fayose ati igbakeji rẹ, to tun jẹ oludije sipo gomina ninu eto idibo to waye ninu oṣu Keje, 2018 ni ipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Oluṣọla Ẹlẹka, ṣe abẹwo si ile Bola Tinubu to wa ni ilu Eko.

Fayose ni fifi iru ẹsun bẹẹ kan oun ko yatọ si ki oun maa ba awọn adigunjale ṣe ọrẹ.

Fayose fi ikede naa sita l'oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ pe...

O ni 'mo si wa ninu ẹgbẹ PDP, gbogbo awọn to ba n so mi pọ mọ APC le tẹsiwaju lati maa ṣe ajọyọ titan ara wọn jẹ ninu oṣelu.

Ati pe 'bo ku ọkunrin kan ṣoṣo ti yoo tako ijọba apaṣẹ wa a Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC, Ayọdele Fayoṣe ni yoo jẹ ọkunrin naa'.