NYSC: Àwọn àgùnbánirọ̀ gbọ́dọ̀ gba àṣẹ kí wọ́n tó ṣètò ìgbafẹ́

Awon agunbaniro

Oríṣun àwòrán, Nysc/twitter

Àkọlé àwòrán,

Ibi ìgbáfẹ́ já sí ibi ikú fún àwọn agànbánirọ̀ mẹ́san an

Ọga agba ajọ agunbanirọ, Ọgagun Suleiman Kazaure kilọ fawọn agunbanirọ lati ṣọra fun irede oru.

O sọrọ yii lẹyin ọkan-o-jọkan iṣẹlẹ aburu lori awọn agunbanirọ lẹnu ọjọ mẹta yii

Kazaure ni ko saye wẹjẹ-wẹmu tabi igbafẹ mọ fawọn agunbanirọ afeyi ti awon alaṣẹ ajọ naa ba fọwọsi.

O ni ibanujẹ lo jẹ fun ajọ naa pe awọn agunbanirọ mẹsan tun ku nipinlẹ Taraba.

"Bi ẹ ba fẹ ṣeto wẹjẹ-wẹmu tabi igbafẹ kankan, ẹ gbọdọ gba aṣẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ agunbanirọ, yala lẹkun ijọba ibilẹ tabi oludari nipinlẹ; aṣẹ mi niyẹn."

Agunbanirọ mẹsan doloogbe nibi igbafẹ

Laipẹ yii ni awọn agunbanirọ mẹsan padanu iku aitọjọ nigba ti ẹkun omi gbe wọn lọ lasiko ti wọn lọ wẹ lodo Moyo Salva fun igbafẹ ní ìjọ̀ba ìbílẹ̀ Gashaka ìpínlẹ̀ Taraba.

Agùnbánirọ̀ mẹ́sàn-án ló ti ṣe pẹ̀kí ọlọ́jọ́ wọn lẹ́yìn tí wọn lo si odo Moyo Salva fún ìgbáfẹ́ ní ìjọ̀ba ìbílẹ̀ Gashaka ìpínlẹ̀ Taraba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpílẹ̀ Taraba, David Missal, ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn agùnbánirọ̀ ló lọ́ fún ìrìnàjò ìgbáfẹ́ ọ̀hún sí odò náà ti omi ọhun si déédé ru kójá bèbè rẹ̀ tí ó si gbé àwọn agùnbánirọ̀ náá lọ

O ní ènìyàn méjìlélógún ló lọ sùgbọ́n méje nínú àwọn tí omi náà gbé lọ ni ó kú ti àwọn méjì sì di àwátì, sùgbọn ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ lati wa wọn. Nínú ọ̀rọ̀ Florence Yaakugh, tó jẹ́ alákoso àwọn agùnbánirọ̀ ní ìpínlẹ̀ náà jẹ́rìsí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, o ní ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àgbófinro àti àwọn òmùwẹ̀ ìlú nàá.

Odò Mayo Selbe ninu aworan yii lo gbe awọn agunbanirọ lọ.

Yaakugh sàlàyé pé kò sí ẹ̀ni tó tii mọ àwọn agùbánirọ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀lẹ̀ sí tan tí àsìkò yìí sí jẹ́ àsìkò ọ̀fọ̀ fún ilé iṣẹ́ agùnbánirọ̀ ní ìpínlẹ̀ Taraba.

Àkọlé fídíò,

Ọmọ Yoruba ni mi

Àkọlé fídíò,

Ṣé ẹ rántí orin - Má ṣe jẹ́jẹ́ ma wà mi lọ?