Wọn dóòlà ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èrò níbi ìṣẹlẹ̀ ilẹ̀ rírì erékúṣù Lombok

Alaisan lori ibusun itọju

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Àwọn olutọju alaisan n gbe alaisan kuro nile iwosan Mataram

Irinajo afẹ́ to di irinajo to n gbẹ̀mí àwọn ènìyàn ni Indonesia.

Odiwọn iye awọn to ti ku nibi iṣẹlẹ ilẹ riri nla to ṣẹlẹ ni Lombok ti di mejidinlọgọrun bayii.

Awọn ti wọn farapa ti le ni igba.

Awọn agbegbe to bajẹ julọ ni bii abule Lading-Lading, ilu Mataram, ati àwọn agbegbe miran ni ariwa Lombok.

Bayii wọn ti ko ọpọlọpọ àwọn èrò lọ kuro ni Gili nibi ti wọn ṣi ti n ko àwọn arinrinajo kuro pẹlu ọkọ oju omi.

Oríṣun àwòrán, @lauramilne

Àkọlé àwòrán,

Àwọn arinrinajo to wa ni Gili Trawangan

Ọpọ àwọn to wa ni erekuṣu naa ni ebi n pa wọn nitori ko si omi to ṣee mu ati ohun jijẹ ni eyi ti awọn eniyan ti n fẹ huwa ipá.

Àkọlé àwòrán,

Erekuṣu Lambok ni Indonesia

Àkọlé fídíò,

Ọdunlade Adekọla gbóṣùbà fáwọn ọkùnrin tó ń ran ìyàwó wọn lọ́wọ́

Àkọlé fídíò,

Fẹla Durotoye: ọ̀rọ̀ ìṣọ̀kan Nàìjíríà tó àpérò ọmọ eríwo

Àkọlé fídíò,

Ṣé ẹ rántí orin - Má ṣe jẹ́jẹ́ ma wà mi lọ?