Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá: ìwádìí bẹ́rẹ́ lórí ikú ọdaran tó tojú orun dójú ikú'

Eni to lo tramadol

Oríṣun àwòrán, @sahara

Àkọlé àwòrán,

Àsùnjí o fún olóorun ajínigbé oní Tramadol

Láti ojú oorun de ojú ikú, ṣe àwọn ọlọpaa ṣe ohun to yẹ?

Ọrọ Yoruba kan lo ni ‘asun fọn-fọn n tifọn, asun-maparada ni ti igi aja’, bẹẹ́ ni ọrọ ri fun ọkunrin ajinigbe naa, ti ẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn, bawo ni iṣẹlẹ naa gan an ṣe waye? Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti Ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Femi Joseph ṣalaye fun BBC Yoruba pe:

Ileesẹ ọlọpa fi ẹsun idigunjale ati ijinigbe kan an. Ati pe wọn sakiyesi pe oogun oloro Tramadol ni o lo nigba ti wọn mu nitori wọn ba saṣẹẹti oogun naa ni apo rẹ.

Ìgbẹ́sẹ̀ àwọn ọlọpaa kí o tó kú

Igba ti wọn si ṣakiyesi pe ko le gbe apa, ko le gbe ẹsẹ, lasiko ti wọn safihan rẹ fun awọn oniroyin ni wọn gbe e lọ sileewosan.

O ni ọjọ ti awọn mu naa ni wọn gbe e lọ sile ìwosan, to si wa nibẹ fun ọjọ mẹsan.

Ati pe, awọn dokita n fa omi si i lara ni gbogbo igba to fi wa nileewosan.

Sugbọn o pada ku ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, lẹyin ọjọ mẹsan.

Àkọlé fídíò,

Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá: ìwádìí bẹ́rẹ́ lórí ikú ọdaran tó tojú orun dójú ikú'

Bawo ni ọwọ́ ṣe tẹ ẹ?

Joseph ni 'ikọ ẹlẹni mẹta naa wọ ile itaja oogun kan ni ìlú Ọ̀wọ̀, nipinlẹ Ondo, pẹlu ibọn lọwọ wọn, sugbọn ti onile itaja oogun naa ti wọn fẹ ẹ jigbe tete pariwo ẹ gbami, to si gba ẹnu ọna mi i sa jade.'

Àkọlé àwòrán,

Àṣìlò òògùn Tramadol ati àwọn mi i bi codeine le ṣe àkóbá fún ara

Awọn akẹgbẹ rẹ meji ti wọn jọ lọ fun iṣẹ buruka naa ja ọkada ẹnikan to wa ra oogun nile itaja oogun naa, ti wọn si gbe e salọ.

Nibi ti oun ti n gbiyanju lati gun ọkada ti wọn ti wọn gbe wa, ni awọn ara adugbo sare le e mu. Bi o se n gbiyanju lati wa ọkada naa kuro nibẹ, ni ko le lọ mọ, to si subu lati ori ọkada.

Ati igba naa ni oogun Tramadol ti n se isẹ ki sẹ lara rẹ.

O ni ayẹwo awọn dokita ni ileewosan General Hospital to wa ni ilu Ọwọ ti wọn gbe e lọ jẹ ki awọn mọ pe oogun naa ti se isẹ buruku lara rẹ.'

Njẹ awọn mọlẹbi rẹ ti wa a gbe oku rẹ?

Joseph ni oku rẹ si wa nileewosan, ti ileeṣẹ ọlọpaa si n duro de ayẹwo lati mọ ohun to ṣekupa, ki wọn to yọnda rẹ fun awọn eniyan rẹ.

Sugbọn nigba ti a bii pe ṣe wọn ti mọ awọn eniyan rẹ, Joseph ni wọn ko ti i mọ wọn.

O ni ọ̀rọ̀ ọkunrin naa da bi ọrọ̀ Yoruba kan to sọ pe 'ko si ẹni to fẹ ẹ fi ọbẹ to nu j'ẹsu.'

Awọn mọlẹbi rẹ kankan ko ti i yọju. O ni ẹẹkan ṣoṣo to laju, 'Iṣẹ́ Olúwa' nikan ni ọrọ to sọ lẹyin ti wọn mu. O ni awọn gbọ pe awọn ara ilu rẹ ko sọrọ rẹ daada.

O ni iku ọkunrin naa dun ileesẹ ọlọpa, nitori pe ko ba ran wọn lọwọ lati jẹ ji ọwọ tẹ awọn akẹgbẹ rẹ to salọ.

Kin lo yẹ ko mọ nipa apọju oogun Tramadol ninu ara ?

Onisegun oyinbo kan, Dokita Kunle Obilade, tile iwosan ijọba ipinlẹ Ọyọ salaye fun BBC wi pe ewu n bẹ loko longẹ ni oogun oloro Tramadol ninu agọ ara.

Oríṣun àwòrán, @kojonyed

  • Tramadol lee wo ara riro san ti eeyan ba mu odiwọn to yẹ ni nilo
  • O maa n kun ọpọ eeyan to ba lo o ni oorun
  • Nigba mii, awọn eeyan miran to lo Tramadol, kii sun
  • Apọju Tramadol kii jẹ ki eeyan mọ ohun to n lọ ni ayika mọ to ba ti denu ara
  • Kii jẹ ki eeyan lee mi jalẹ nigba miran
  • Tramadol lee tete ge ẹmi kuru, ko si pa eeyan
  • Tramadol se e fà kuro ninu ara ti ko ba tii sisẹ́ dapọ̀ mọ̀ ẹ́jẹ