Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀ọ́tọ̀ lórí ohun tó n wáyé l'ágbo òṣèlú

Bola Tinubu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Tinubu ni 'ki awọn to n gbimọ ìkà jawọ, nitori pe 'ko ni ṣeeṣe fun alangba lati ba igala ja; mo ki ara mi kú iṣẹ́ ni Eko'

Tinubu: kí ló dé ti Ọbasanjọ kò ṣe fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ lásìkò rẹ̀?

Oloye Bola Tinubu to jẹ àgbà egbẹ fun APC ti fun Oloye Oluṣegun Obasanjọ to jẹ aarẹ Naijiria nigba kan ri ni esi lẹta to kọ si Buhari to n tukọ Naijiria.

Tinubu fi ẹsun kan Obasanjọ pe ka ni o ti ṣe ipilẹ to dara silẹ fun iṣelu awa-ara-wa lasiko to n ṣe aarẹ ni, gbogbo wahala oṣelu yii ko ni si nibẹ.

O ṣiṣọ loju ọ̀rọ̀ naa nile ẹgbẹ APC nilu Eko lasiko ipade awọn ọmọ ẹgbẹ nibi to ti fi ara rẹ ṣe apẹrẹ pe ipilẹ rere ti oun fi silẹ gege bi gomina nipinlẹ Eko lo di òpó oṣelu mu bayii nipinlẹ Eko.

O ni wọn maa dibo abẹle yan ẹni to wu wọn gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko ni ti asiko ba tó pẹlu ileri pe àwọn to se daadaa ninu oloye ẹgbẹ yoo ni anfani lati lọ leekeji.

Tinubu dagbere fawọn to n ya kuro ni APC

'Kò ṣéèṣe fún aláǹgbá láti bá ẹtu jà' ni ọrọ idagbere Bola Tinuba fun àwọn to n ya kuro ni ẹgbe oselu APC ni eyi to tun fi n ki awon to ṣẹṣẹ n darapọ mọ ẹgbẹ kaabọ sile.

Tinubu gbà pé ó ṣoro láti ko ìwo ẹkùn lé ajá lọ́wọ́

Adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu, ti fẹsun kan awọn kan lara awọn ọmọ ile aṣofin, pe wọn n gbero lati yọ Aarẹ Muhammadu Buhari l'oye.

Tinubu sọrọ naa ni Ọjọru nibi ayẹyẹ igbaniwọle fun olori ọmọ ile to kere ju nile aṣofin agba Naijiria, Sẹnetọ Godswill Akpabio, to waye ni papa iṣere Ikot Ekpene, nipinlẹ Akwa Ibom.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu ni 'ki awọn to n gbimọ ika jawọ, nitori pe 'ko ni ṣeeṣe fun alangba lati ba ẹtu ja.'

Image copyright @SenGbengaAshafa
Àkọlé àwòrán Akpabio ni ọmọ ẹgbẹ PDP to nipo julo to fi ẹgbẹ silẹ lọ si APC Lẹnu ọjọ mẹta yi

O ṣapejuwe ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ ni Naijiria gẹgẹ bi 'ogun laarin awọn onilọsiwaju ati awọn to wa l'oju kan.

O ni 'a gbagbọ ninu ijọba awaarawa, sugbọn awọn to wa l'oju kan ni igbagbọ nilu iṣejọba pipin owo ilu laarin awọn kan, to fi mọ jiji owo orilẹede Naijiria ko sapo ara wọn.

Irinajo tuntun bẹrẹ fun Akpabio

Saaju ni Akpabio to jẹ Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere ju nile igbimọ aṣofin agba Naijiria, ti kọwe fipo rẹ silẹ, ko to di pe o kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Ọjọru, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, 2018.

Ni papa isere Ikot Ekpene ni wọn ti n ṣe ayẹyẹ ikini kaabo sinu ẹgbẹ fun un ni ipinle Akwa Ibom.

Ọgọrọ ọmọ ẹgbẹ oselu APC ati awọn eekan ẹgbẹ ni wọn pejo sibi ayẹyẹ naa

Lọjọ Aje ni awọn aworan kan ti kọkọ jade sita, eyi to ṣafihan Godswill Akpabio pẹlu Asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu.

Image copyright @SenGbengaAshafa
Àkọlé àwòrán Awọn Sẹnẹtọ ọmọ ẹgbẹ APC kọwọ rin pẹlu Akpabio

Kíni awọn ọmọ Naijiria n sọ?

Awọn ọmọ Naijiria ko tilẹ jẹki ayẹyẹ naa pari ki wọn to bẹrẹ iriwisi loju opo Twitter.

E gbọ naa, ẹgbẹ wo ni Akpabio fi silẹ lati lọ darapọ mọ omiran? Ọrọ naa polukurumusu mọ awọn kan loju debi wi pe wọn n gbe ẹgbẹ si ara wọn.

Ni kiakia lawọn oloju kogberegbe ti sare tọka si asikọ yii.

Awọn eeyan kan kan saara fun un bi ero ti se pọ nibi ayẹyẹ ọhun ti wọn si ni ifasẹyin ni kikuro ninu ẹgbẹ Akpabio yoo jẹ fun PDP.

Bi ẹrin ni awọn kan fi ọrọ naa ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Ṣaaju eyi ni Akpabio lọ si ilu London lati lọ ki Aarẹ Muhammadu Buhari to wa lẹnu isinmi.

Eyi si ti mu ki awọn kan maa sọ pe boya o fẹ fi ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP, silẹ lati darapọ mọ APC.