Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

'Mo kọ̀ láti jẹ́ ki ipenija yii sọ mi di alágbe'

Ṣeun Ogundiya sọrọ lori igbesẹ akin to gbe lati lọ kawe nipa iṣẹ olukọni NCE ati ni fasiti OAU ni Ile Ife léyin iṣẹlẹ to gbe oun sori kẹkẹ fun BBC Yoruba.

O rọ àwọn Dokita lati mu iṣẹ wọn ni ọkunkundun láì ba ayé àwọn alaisan jẹ́ nitori pe 'Bayii kọ ni wọ́n ṣe bi mi o!'.

O gba gbogbo àwọn ti wọn ni ipenija oriṣii lati ma ṣe sọ ìrètí nù rara.

Ní ipari Ṣeun Ogundiya rọ àwọn eniyan ki wọn dẹkun ìdẹ́yẹsí àwọn ti wọn ba ni ipenija ara nitori pe kò wù wọn bẹ́ẹ̀ rara.