Izeowayi gb'ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lórí ìdíje àròkọ BBC Pidgin:

Izeowayi Victor àti awọn oṣiṣẹ BBC
Àkọlé àwòrán,

Ìdíje àròkọ̀ ni BBC Pidgin

Ọgbẹni Izeowayi Victor lo jawe olubori ninu idije arokọ ni ede Pidgin.

Ìdíje yii wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ti pé tàbí ju ọmọ ọdún mejidinlogun lọ.

Àkọlé àwòrán,

BBC, erin nla to n ṣeun nla lawujọ

Izeowayi lo gba ami ẹyẹ naa ninu awọn akẹẹkọ mejidinlogun to kopa ninu idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akori arokọ naa ni: Ṣé Ọ̀dọ́ Afrika ti ṣetán fun ipò adarí nínú òṣèlú?

Akẹẹkọ Victor gba ẹbun ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fun ọdun kan pẹlu owó iwe ti yoo lo pata lẹyin to jawe olubori ninu idije naa.

Eyi ni igba akọkọ ti iru idije yii yoo waye lati igba ti BBC Pidgin ti bẹrẹ.

Adari ile isẹ BBC lapa iwọ-oorun Afirika, Toyọsi Ogunṣẹyẹ, rọ awọn ọdọ lati maa kopa ninu ṣiṣe ipinnu l'orilẹede Naijiria nipa lilọwọ si ohun to n ṣẹlẹ layika wọn.

Àkọlé àwòrán,

Ebun nla n duro de ẹni to ba bori

Bawo ni idije naa ṣe lọ?

Kọ arokọ ọ̀rọ̀ to to ẹẹdẹgbẹrin si ẹgbẹrun kan (800-1000 words) ranṣe lede Pidgin si bbcpidgin.essay.bbc.co.uk

Rii pe ko si ọrọ ija, ọ̀rọ̀ aworan iwokuwo/iṣekuṣe (Pornography), igbesunmọmi, ohunkohun to le ba awujọ jẹ tabi rogbodiyan ninu arokọ rẹ.

Kọ orukọ rẹ, nọmba rẹ, adirẹsi ilé rẹ, koko arokọ ti o n kọ, àti gbolohun diẹ nipa ara rẹ ni eyi ti BBC yoo lo fun idije yii nikan ṣoṣo.

Idije yii bẹrẹ lojo Aje, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ yoo si pari ni ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu kẹsan, ọdun 2018 ni agogo 23:59 GMT.

BBC Pidgin yoo kan si ẹni to ba gbegba oroke laarin ọjọ kẹwaa si ọjọ kejila, oṣu kẹsan an, ọdun 2018.

Àkọlé àwòrán,

Igba akọkọ ti a maa ṣe eyi niyi

Ọna wo ni o le fi yege?

Ko arokọ rẹ daadaa ni ede PIDGIN.

Mo itan sọ daadaa.

Mọ ilana bi a ṣe n kọ arokọ ni kikun.

Tẹle ilana ofin girama ede Pidgin bi o ti yẹ.

Idije yii ko si fun oṣiṣẹ BBC kankan ati awọn ẹbi wọn rara.

Oríṣun àwòrán, @istock

Àkọlé àwòrán,

Ẹni ba láyà