Yusuf Magaji Bichi di Olùdarí àgbà tuntun

Yusuf Bichi Image copyright @BysShuwaki
Àkọlé àwòrán Yusuf Bichi

Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ti ní Olùdarí àgbà tuntun.

Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Kẹsàn án ni Àárẹ Muhammmadu Buhari buwọ́lu ìyànsípò Yusuf Magaji Bichi, gẹ́gẹ́ bi Olùdarí Àgbà fún àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí iléèṣẹ́ Ààrẹ fi síta lójú òpó Twitter ni wọ́n ti kéde ìyànsípò Magaji Bichi.

Ìyànsípò Bichi wáyé lẹ́yìn tí wọ́n yọ Olùdarí Àgbà fún àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS tó wà nípò tẹ́lẹ̀, Lawal Daura kúrò nípò rẹ̀.

Kò yá wà lẹ́nu pé Dogara lọ sí PDP

Ambọde: Kò sí ìjà láàrin èmi àti Tinubu

Igbákejì Àárẹ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọṣinbajo ló gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Daura l'ọ́jọ́ keje, oṣù Kẹjọ, 2018, lásìkò tó fi delé fún Ààrẹ Buhari tó lọ fún ìsìnmi ẹnu iṣẹ́ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ìgbésẹ̀ yíyọ Daura níṣẹ́ wáyé lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ DSS kan yabo ilé ìgbìmọ̀ asọfin Nàìjíríà, tí wọ́n sì dí ọ̀nà mọ́ àwọn aṣòfin.

Image copyright dss
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá àgbà tuntun nàá gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò òṣèlú nílé ẹ̀kọ́ gíga fásìtì Ahmadu Bello tó wà nílùú Zaria.

Lẹ́yìn awuyewuye yìí ni Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Bukọla Saraki, àti àwọn aṣòfin mìíràn fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress sílẹ̀ tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Peoples Democratic Party, PDP.

Àwọn àmúyẹ wo ni Ọ̀gá DSS tuntun, Yusuf Magaji Bichi ní ?

Ọ̀gá àgbà tuntun nàá gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò òṣèlú nílé ẹ̀kọ́ gíga fásìtì Ahmadu Bello tó wà nílùú Zaria.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò àábò ní ìlú Kano, lẹ́yìn èyí ló sì darapọ̀ mọ́ àjọ elétò àábò Nigerian Security Organization (NSO), tó ti kógbá sílé báyìí.

Àjọ NSO ni a mọ̀ sí àjọ Director of State Service (DSS).

Ọ̀gbẹ́ni Bichi ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ṣíṣe àtúpalẹ̀ àbọ̀ ìwádìí iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, tó fi ma nípa ètò ìgbanisíṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ilé ìwòsàn ṣi abẹ́rẹ́ Formalin gún mí; n kò lè dá ìgbẹ́ àti ìtọ̀ dúró mọ́'

Ọ̀gá àgbà DSS tuntun ọ̀hún ni iléèṣẹ́ Ààrẹ́ ní yóò ṣe àmúlò àwọn ìrírí tó ti ní nínú iṣẹ́ ìwádìí, àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí, ìpẹ̀tù sí àáwọ̀, ìpèsè àábò,tó fi mọ́ kíkópa nínú àwọn ìṣẹ́ tó léwu àti èyí tó jẹ́ ẹlẹgẹ́.

Bichi ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Olùdarí àjọ DSS ní ìpínlẹ̀ Jigawa, Niger, Sokoto àti Abia.

Bákan nàá lo ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Olúdarí Ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti n kọ́ nípa ogun jíjà (National War College), tó fi mọ́ iléèwé tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ DSS, àti àwọn ẹ̀ka mì í tó wà nínú àjọ DSS.

Àwọn awuyewuye tó jẹyọ̀ lórí Lawal Daura kí wọ́n tó yọ ọ́ níṣẹ́

Iyansipo Lawal Daura gẹgẹ bi ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lọdun 2015, mu awuyewuye dani.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fi oju aitọ wo o, nitori pe ipinlẹ Katsina l'oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti jọ wa, ati lori 'aikoju oṣuwọn rẹ fun iṣẹ naa'.

Bakan naa lo jẹ wi pe Daura ti fẹhinti kuro lẹnu iṣẹ nileeṣẹ ajọ DSS, ko to di pe Buhari tun pe e pada. O tun jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ fun eto aabo ati ọtẹlẹmuyẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lasiko eto idibo ọdun 2015.

Lati igba to si ti bẹrẹ iṣẹ ni awuyewuye loriṣiriṣi ti n jẹyọ lori ihuwasi rẹ.

O tako iyansipo alaga ajọ EFCC

Daura tun kọ iwe ẹsun si ile aṣofin nipa ọga agba ajọ EFCC, Ibrahim Magu, eyi to mu ki awọn 'koju oro si iyansipo rẹ.'

Ta ló wà nidi wàhálà ílé aṣòfin Nàíjíríà?

Irú ẹ̀dá wo ni aṣòfin Bukola Saraki jẹ́?

Eto igbanisiṣẹ ajọ DSS

Awuyewuye jẹyọ lori eto igbanisiṣẹ awọn oṣiṣẹ ọrinlenirinwo din ẹyọkan, 479, tuntun fun ajọ DSS.

Ninu 479 ni ipinlẹ Katsina ti ni eniyan mọkanlelaadọta, 51, eyi to ju ida mẹwa gbogbo awọn ti wọn gba siṣẹ jake-jado Naijiria lọ.

Ọpọlọpọ lo bu ẹnu ẹtẹ lu Daura nigba naa pe bawo ni ipinlẹ Katsina, to jẹ ipinlẹ rẹ yoo ṣe ni to bẹ ju awọn ipinlẹ yooku lọ.

Oun ati ajọ EFCC naa jọ woju ara wọn.

Wọn fi ẹsun kan iṣakoso rẹ fun obitibiti biliọnu Naira ti wọn fi kọ ile ẹkọ DSS ni ipinlẹ Katsina; kikuna lati jẹ ki olubadamọran lori eto aabo Naijiria nigba kan, Sambo Dasuki, wa sile ẹjọ lati jẹri lori awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu iwabajẹ.

Ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ajọ DSS da awọn oṣiṣẹ ajọ EFFC duro lati maa fi ofin gbe Ita Ekpeyong, to jẹ Ọga agba ajọ DSS tẹlẹ, lai fi ti pe wọn ni aṣẹ lati mu u ṣe.

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ keje, oṣù Kẹjọ ni Adele Aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀

Bakan naa ni wọn ko jẹ ki wọn o fi ofin gbe Ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ National Intelligence Agency, NIA, Ayodele Oke, ti Aarẹ Buhari da duro lẹnu iṣẹ.

Ẹsun kikowo ilu jẹ ni ajọ EFCC nwa ọga agba DSS ọhun fun.