Ademọla Adeleke: Àwọn akẹẹgbẹ́ mi ní iléẹ̀kọ́ girama mọ̀ mi bíi ìsáná ẹlẹ́ẹ́ta

Sẹnetọ Ademọla Adeleke Image copyright @IsiakaAdeleke
Àkọlé àwòrán Adeleke ni oun lọ si fasiti kan ni ilẹ Amẹrika lai lo iwe ẹri oniwe mẹwa Waec ti oun ni

Ademọla Adeleke, tii se oludije fun ipo gomina labẹ́ẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ọsun sọrọ lẹyin idajọ ile ẹjọ nipa iwe ẹri rẹ.

Adeleke ni oun lọ si fasiti kan ni ilẹ Amẹrika lai lo iwe ẹri oniwe mẹwaa WAEC ti oun ni.

Ilu Ẹdẹ ni Adeleke ti sọrọ yii lasiko to n fesi nipa iwe ẹri rẹ, ti meji ninu awọn akẹẹgbẹ rẹ ni ile ẹkọ girama Ẹdẹ Muslim Grammar School, si rọgba yii ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn ọkẹẹgbẹ oun ni ile ẹkọ girama naa da oun mọ, bii isana ẹlẹẹta, nitori odu ni oun nile ẹkọ naa, kii se aimọ fun oloko, taa ba n sọrọ ọrọ idaraya.

Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ọsun naa wa sisọ loju rẹ pe, bi oun yoo se lọ si ile ẹkọ giga ni ilẹ Amẹrika lo mumu laya oun nigba naa, ti oun ko si duro ki esi idanwo waec oun jade, ti oun fi lọ

O wa foju laifi wo igbesẹ bi wọn se n beere iwe ẹri oun, to si se apejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bii ‘iwa agabagebe ati ẹtan

Bẹẹ ba gbagbe, Ileẹjọ ti fun Sẹnetọ Adeleke to n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni aṣẹ maa niṣo ko sewu lori ẹsun ayederu iwe ẹri ti wọn fi kan an.

Onidajọ David Oladimeji, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun, ninu idajọ to gbekaẹ lọjọọru ile ẹjọ naa ko lee kaa lọwọ ko lori erongba rẹ lati dije fun ipo gomina nitoripe olupẹjọ kuna lati fi idi ẹsun ayederu iwe ẹri to fi kan an mulẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnídájọ́ Fọlahanmi Oloyede léwájú ìwọ́de òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì fún ọjọ́ mẹ́ta l'Ọ́ṣun

Onidajọ Ọladimeji ni lootọ iwe ti olupẹjọ gbe kalẹ niwaju ile ẹjọ naa ni "ọpọlọpọ kotọ to lagbara gidigidi" sibẹ ile ẹjọ ko lee doju rẹ kọ oorun alẹ lori didije fun ipo gomina.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP meji kan, rasheed Ọlabayọ ati Idowu Oluwaseun, ni wọn gba ile ẹjọ lọ pẹlu ẹbẹ pe ki ileẹjọ paṣẹ lati da Adeleke lọwọkọ gẹgẹ bii oludije PDP ninu idibo sipo gomina nipinlẹ Ọṣun eleyi ti yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu kẹsan, ọdun 2018.

Image copyright @IsiakaAdeleke1
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP meji kan, rasheed Ọlabayọ ati Idowu Oluwaseun, ni wọn gba ile ẹjọ lọ pẹlu ẹbẹ pe ki ileẹjọ paṣẹ lati da Adeleke lọwọkọ gẹgẹ bii oludije PDP

Adajọ ni oun rii pe olujẹjọ naa, iyẹn sẹnetọ Ademọla Adeleke, ka iwe de ipele girama eleyi to ni o fi han ninu iwe ibura to fi ran'sẹ si ile ẹjọ naa.

O ni olupẹjọ ko gbe ẹsun dide lori ayederu iwe ẹri ninu ẹjọ to kọkọ pe; o si kuna lati fi idi rẹ mulẹ pe ayederu ni iwe ẹri to fihan.