Saraki: Àwọn kan n hùwà tani-ó-múmi ni Aso Rock lábẹ́ Buhari

Bukọla Saraki Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn aṣofin apapọ fun iwa akin ti wọn hu.

Saraki ní ijọba miran wà nínú ijọba Buhari

Aarẹ ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki ni awọn eeyan kan ti gbe ijọba ara wọn kalẹ laarin ijọba ti Aarẹ Muhammadu Buhari eyi ti araalu mọ.

Saraki sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nibi ipade to pe nilu Abuja.

O ni APC ló wà nídí ilé aṣòfin àpapọ̀ t'áwọn agbófinro dí pa.

Saraki ni pẹlu bi awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, awọn aṣofin apapọ atawọn oṣiṣẹ ile aṣofin ṣe dide tako awọn ohun to pe ni iwa familete-n-tutọ, lo tubọ mu ki igbẹkẹle oun ninu awọn eeyan orilẹ-ede yii gbopọn sii.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán 'APC ló wà nídí ilé aṣòfin àpapọ̀ t'áwọn agbófinro dí pa'

"Bi ẹ ba ranti pe ni ọdun meji sẹyin mo pariwo sita pe awọn eeyan kan ti gbe ijọba kalẹ laarin ijọba aarẹ Buhari atipe iṣẹ ati iṣe wọn lo ti wa n farahan bayii.

O jẹ iyalẹnu nla pe olori ajọ kan yoo kan dede dide lati paṣẹ pe ki wọn ṣigun lu ile aṣofin apapọ gẹgẹbi a ti ṣe rii lana."

Sẹnetọ Saraki ko ṣai kan sara si adele-aarẹ Yẹmi Oṣinbajọ fun igbesẹ akin to gbe lati daabo bo iṣejọba tiwantiwa eleyi to ni o mu ọpọ ifọkanbalẹ wa; ṣugbọn ko tii 'dahun ibeere lori bi iwa kotọ yii ṣe waye gan.'

O wa pe fun iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa pẹlu afikun ipe fun fifi gbogbo awọn ti wọn ba mu jofin.

Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC pe o n gbiyanju lati da oju iṣejọba tiwantiwa bolẹ pẹlu bi o ṣe ṣigun bo ile aṣofin agba pẹlu awọn agbofinro ọtẹlẹmuyẹ ni ọjọ iṣẹgun.

Saraki, ninu ọrọ to sọ lasiko ipade iroyin agbaye to ṣe nilu Abuja ṣalaye wi pe awọn sẹnetọ kan labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lo fẹ gbiyanju ati yọ oun nipo ni wọn lo ile-eṣẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ lati fi dukuku mọ awọn aṣofin ti wọn si se ọna to wọ ile aṣofin apapọ.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn aṣofin apapọ fun iwa akin ti wọn hu eleyi to ni wọn fi daabo bo eto ijọba tiwantiwa lorilẹ-ede Naijiria

Kí lẹ ò mọ̀ nípa àwọn obinrin Yollywood yìí?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌgbésí ayé àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyìí di ọ̀tun láti 2008