DBanj: Ikú ọmọ mi kò leè paná ìfẹ́ láàrín èmi àti ìyàwó mi

Dbanj lode ere kan Image copyright @Dbanj
Àkọlé àwòrán DBanj ni lootọ ni nnkan ko rọgbọ latigba ti ọmọ oun ọkunrin ti ku

D Banj: àdánwò kò lè ṣalai má de ba ẹ̀dá láyé

Gbajugbaja olorin takasufe ni, Dapo Daniel Oyebanjo ti ọpọ mọ si DBanj ti sọ pe iku ọmọ ohun to waye laipẹ yii ko lee ya ifẹ oun ati iyawo oun, Lineo.

Ninu awo orin tuntun to gbe jade, diẹ ninu eyi to fi sori oju opo Instagram ati twitter rẹ, DBanj ni gbogbo ipenija yoowu ti o lee koju oun tabi ẹbi oun, iyawo oun ni iyawo oun yoo ma jẹ o.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

'Mímu ọyàn àyà ìyàwó rẹ̀ ní àǹfàní tó pọ̀'

Kò sáyè ìgbafẹ́ mọ́ fáwọn àgùnbánirọ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́

Olorin takasufe naa tun jẹ ko di mimọ ninu ọrọ pelebe to kọ sori ikanni Instagram rẹ pe, " A o jumọ la gbogbo idanwo ti a ba n koju kọja ni. Eyi ni fun iwọ iyawo mi #WhatYouWant #LetterToMyWife #Everything #MamaDaniel 8/8/18.''

Image copyright Dbanj
Àkọlé àwòrán Oṣu kẹfa, ọdun 2018 ni Daniel, ọmọ ọkunrin DBanj ku lẹyin oṣu diẹ to ṣe ọjọ ibi ọdun kan rẹ.

Orin yii n wọle lẹyin ọjọ diẹ to ṣe akọsilẹ ohun ti oju ẹbi rẹ ri ati ọna ti o n gba wẹ ọgbẹ ajalu iku ọmọ rẹ ninu atẹjade kan to fi sita lori ikanni instagram rẹ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ latigba ti ọmọ rẹ ọkunrin ti ku.

Image copyright Dbanj
Àkọlé àwòrán Dbanj ni gbogbo ipenija yoowu ti o lee koju oun tabi ẹbi oun, iyawo oun ni iyawo oun yoo ma jẹ o

Lati igbayi wa, DBanj yẹra fun ikanni ayelujara gbogbo titi di ibẹrẹ oṣu keje to gbe atẹjade kan jade ninu eyi to ti dupẹ fun atilẹyin gbogbo eeyan to ṣugbaa rẹ.

'Ọṣinbajo jọmí lójú pẹ̀lú ìwà akin tó hù'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Related Topics