Ǹjẹ́ jìbìtì ti lù ọ́ lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ rí?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

SMS alert: Wo ọ̀nà láti dẹ́kun jìbìtì lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ

Àwọn oníjìbìtì gba ọ̀nà àrà ń ji owó nípa àtẹ̀jíṣẹ́ SMS.

Pẹlu bi iroyin ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS banki ṣe di gbọnmọgbọnmọ lorilẹ-ede Naijiria bayi leyi ti awọn gbajuẹ fi n ṣ'ọṣẹ fawọn ọmọ Naijiria to jẹ onibara awọn banki gbogbo.

Pupọ awọn ti o gba ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS lati ọdọ awọn ọbayejẹ yii ni wọn maa n rope banki awọn lo fi iwe bẹẹ ran'sẹ lai ni ṣe ayẹwo to kunna lori rẹ.

Image copyright Getty Images

Kini awọn ọṣẹ́ ti awọn gbajuẹ ti fi awọn araalu ṣe?

Fun apẹẹrẹ, irufẹ lẹta atẹjiṣẹ bẹẹ lawọn gbajuẹ naa ti fi ranṣẹ ti wọn si n dibọn gẹgẹ bii onibara to fẹ ba wọn dowo pọ; lẹyin ti wọn ba si ti ṣe adehun owo tan ni wọn yoo wa fi ayederu lẹta atẹjiṣẹ ranṣẹ pe awọn ti san owo si inu aṣuwọn ifowopamọsi wọn ki wọn fi ọja ranṣẹ.

Laipẹ yii ni ọwọ tẹ afurasi gbajuẹ kan ti apejẹ rẹ n jẹ 'Wlae Dolla' fun lilo ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS ranṣẹ lati lu oniṣowo owo ṣiṣẹ kan, Abdulhamid Abubakar ni owo to to Miliọnu marun naira.

Gẹgẹ bii ọrọ ti ajọ EFCC fi sita lori iṣẹlẹ naa, iwadii fihan pe ẹgbẹ ajumọṣe awọn gbajuẹ kan ni Ọlaide yii wa ti wọn ko si ni iṣẹ meji ju ki wọn lu awọn eeyan ni jibiti nipasẹ ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS.

Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán SMS atẹjide ti di eyi ti gbajuẹ n lo fi ṣe ọṣẹ́ lasiko yii

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọna mẹta ti o lee fi da ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS mọ...

  • Ki ni apapọ iye owo to wa ninu asunwọn ifowopamọsi rẹ.
  • Ki ni orukọ banki bikoṣe nọmba ipe ẹni to fi ranṣẹ
  • Apapọ rẹ pẹlu iye owo to ba wa ni aṣuwọn ifowopamọsi rẹ kii ba ara wọn mu.

Bakan naa ni okiki dokita iṣegun oyinbo kan naa kan pe oun pẹlu lo ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS lati fi ra awọn ọkọ ayọkẹlẹ ati lati ko owo awọn eeyan lori ẹrọ ayelujara.

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Edgal Imohimi to foju rẹ han ni Ikẹja ni orilẹede Canada ni oun ti kọ iṣẹ ole ori ẹrọ ayelujara.

Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Iwa jibiti ọkan awọn eeyan lo n faa ti wọn fi maa n bọ sọwọ awọn alagbeda yii

Ọna wo lo lee gba daabo bo ara rẹ

Ni imọ nipa iye owo to wa ninu aṣuwọn ifowopamọ sii rẹ

Maṣe gba idokoowo tabi ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS ti o ko pe fun laaye

Fi ohunkohun to ba ru ọ loju nipa aṣuwọn ifowopamọ sii rẹ tabi lẹta atẹjiṣẹ SMS yoowu ti o ba gba to ẹka banki rẹ to wa lagbetgbe rẹ leti.

Kini ero awọn akọṣẹmọṣẹ lori ọrọ yii?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipenija ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS yii ti da awọn akọṣẹmọṣẹ si hilahilo.

Ipenija ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS yii ti da awọn akọṣẹmọṣẹ si hilahilo.

MUHAMMED ISHIYAKU SHEIKH to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ banki, ileeṣẹ adojutofo atawọn ileeṣẹ iṣuna gbogbo lorilẹede Naijiria, NUBIFE ṣalaye fun BBC Yoruba pe aisi aabo to peye fun eto banki ayelujara lati ipilẹ kun ohun to n fa wahala ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS tawọn gbajuẹ n lo yii.

"Ohun ti eyi n fi han ni aisi idagbasoke to peye lori ilana iṣuna igbalode lorilẹede yii. O si fihan pe o yẹ ki awọn ajọ gbogbo ti ọrọ iṣuna kan lorilẹede yii titi fi kan banki apapọ tun ṣokoto wọn san lati rii pe wọn ṣe eto abo to peye fun owo awọn onibara wọn."

Image copyright EFCC

O ni orilẹ-ede yii ṣi nilo awọn ofin to duro daradara lati gbe awọn araalu nija lọwọ awọn gbajuẹ yii ati pe ọrun banki ni wahala wa bi ohunkohun ba ṣe owo ti onibara ba fi si ikawọ wọn.

Ninu ọrọ tirẹ, Aṣofin Tunde Olataunji, to jẹ onimọ nipa iṣuna, ṣalaye fun BBC Yoruba pe, iwa jibiti ọkan awọn eeyan lo n faa ti wọn fi maa n bọ sọwọ awọn alagbeda yii.

O ni aisi ilanilọyẹ to to ati aisi itẹlọrun lawujọ kun ara ohun ti o n fa ọpọ jibiti ayederu lẹta atẹjiṣẹ SMS lawujọ.