Ìgbẹ̀yìn Joe, akínkanjú to dóòlà ẹ̀mí èèyàn 13 ni P/Harcourt

Joe Blankson ati ìyàwó rẹ̀, Mercy, pẹ̀lú ọmọ wọn Owen, nígbà tó wà ọdún méjì Image copyright FACEBOOK/JOE BLANKSON
Àkọlé àwòrán Ọdun maarun sẹyin ni Blankson ati Mercy sẹgbeyawo, ti wọn si bi ọmọ mẹta,

Àwọn ti akọni orí omi Blankson dóòlà ẹ̀mí wọn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ètò ìpèsè ààbò lórí omi fáwọn èrò.

Idasefiema Ibimina, Chinonso Cecelia Ndukwe ati Odelusi Bunmi Joy jẹ mẹta lara àwọn ti Blankson to doloogbe lẹyin to gba awọn ero ori omi là kọ̀ lati jẹ ki ikú rẹ̀ ja si asan.

Awọn mẹtẹẹta wa lara awọn ero ti wọn ri sodo Bakana lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje lasiko ti Blankson gba awọn mẹtala là.

Àkọlé àwòrán Agbaagba mẹta to wà nidi ẹẹta pe ki iku Blankson lodo Bakana ma ja si asán

Wọn ni ẹ̀rù omi ti ń ba àwọn lati igba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ, ṣugbọn bayii, wọn fe bẹrẹ ajọ aranilọwọ ti kii ṣe tijọba 'Boat Safety Minders Foundation' ti wọn yoo fi ṣeto iwe akọsilẹ awon arinrin ajo ọkọ oju omi tori iṣẹlẹ idagiri bayii.

Wọn yoo tun maa ṣeto ilanilọyẹ nipa eto aabo fun ẹmi loju omi ni Pọtá pẹlu iranlọwọ awọn ara ìlú.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌbìnrin tó fẹ́ ṣojú àwọn ẹ̀yà Sheedi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSMS alert: Wo ọ̀nà láti dẹ́kun jìbìtì lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ

Opó Blankson, Mercy sọ̀rọ̀ lórí Blankson ọkọ rẹ̀

'Ikú ọkọ mi kò gbọdọ̀ já si asàn ni Nàìjíírà'

Mercy, opó arakunrin Joe Blankson ni bi ala lo ṣi n ri l'oju oun.

Ọgbẹni Blankson, ni ọpọlọpọ ti gboriyin fun gẹgẹ bi akọni to ṣubu loju ija lasiko to n doola awọn eniyan ti ọkọ oju omi ti wọn wọ doju de sinu odo nilu Port Harcourt.

Blankson nikan l'oku ninu ijamba ọkọ oju omi naa to waye l'ọjọ Abamẹta naa.

Mercy, sọ fun BBC pe oun ti ọkọ oun ṣe ko ya oun lẹnu, nitori ọkọ oun maa n fi gbogbo igba ran ọmọnikeji lọwọ ni.

Ọdun marun sẹyin ni Blankson ati Mercy sẹgbeyawo, ti wọn si bi ọmọ mẹta, sugbọn akọbi wọn obinrin di oloogbe l'oṣu Kejila, 2016.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒgidì ọmọ Yorùbá gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ rẹ̀ ni àṣà àti ìṣe Yorùbá

Mercy ni 'oun ko ti i fi tara-tara gbagbọ pe ọkọ oun ti ku , nitori nigba mi i, o maa n ṣe oun bi pe yoo rin wọle wa ba oun.

O ni ile awọn ṣofo lai si ọkọ oun. ati pe " l'ọjọ kan ni ọmọ mi ọkunrin, Owen, gbe baagi rẹ pe oun n wa baba oun lọ si Bakana."

Bawo l'oṣe gbọ pe ọkọ rẹ ku?

Ni ọjọ buruku, eṣu gbomi mu ọhun, Mercy ni ọkọ oun sọ fun oun pe oun yoo gba ibi iṣẹ lọ si Bakana fun eto isinku.

Ṣugbọn, nigba ti ilẹ ṣu ti Joe ko pe gẹgẹ bi iṣe rẹ ni wọn to bẹrẹ si ni bẹru pe boya nkan ti ṣẹlẹ si. Wọn pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, sugbọn ko lọ.

Image copyright Mercy Blankson/Facebook
Àkọlé àwòrán Mercy, aya oloogbe Blankson ni o da bi ẹni pe awọn ri awọn apẹẹrẹ ki iṣẹlẹ buruku naa to waye.

Koda, awọn ọrẹ rẹ ti Mercy pe, ko ri nkankan sọ lori ibi ti o wa.

Laipẹ ni iya Joe wa sọ fun un pe ọkọ oju omi kan danu sinu odo ni Bakana, ti ọkọ rẹ si wa lara awọn ti o wa ninu rẹ, sugbọn wọn ṣi n wa.

Eyi mu ki o nireti pe wọn yoo si ri ọkọ rẹ laaye.

Igba to lọ sile iya ọkọ rẹ, o ri ọpọ eniyan to ko rajọ, ti wọn si n sunkun. Sibẹ, wọn sọ fun un pe wọn ko ti i ri ọkọ rẹ.

Ọjọ Aje, ọgbọnjọ, oṣu Keje, ni iyawo ẹgbọn ọkọ rẹ kan ṣẹṣẹ sọ fun un pe ọkọ rẹ ti ku lẹyin ti awọn pẹja-pẹja ri oku rẹ to lefo soju odo.

Ibanujẹ bẹrẹ wayii

O sare lọ si ibudokọ omi Abonnema, ṣugbọn wọn ko jẹ ko ri oku rẹ nitori pe o n t'ọmọ lọwọ.

Bakan naa ni aṣa sọ pe ki wọn o sin oku ẹnikẹni to ba ku sinu odo si eti odo naa. Nitori eyi, ko mọ ibi ti wọn sin ọkọ rẹ si.

Mercy ni awọn ti ri awọn apẹẹrẹ ki iṣẹlẹ buruku naa to waye.

Àkọlé àwòrán Odo Abonnema ni Bakana to di oju oori Blankson

O ni awọn lọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi ni ọsẹ ti Joe ku. O si sọ fun ọkọ rẹ pe o da bi ẹni pe nkan buruku kan yoo ṣẹlẹ laipẹ, nitori pe igba ti awọn lọ si agbegbe naa kẹyin, ijamba ina kan waye to mu ẹmi akọbi wọn obinrin lọ.

Àkọlé àwòrán Kii si akọsilẹ odiwọn iye ero to n wọnu ọkọ oju omi ni Bakana

Ṣugbọn, ọkọ rẹ ni ko fi ọkan balẹ, pe nkankan ko ni i ṣẹlẹ. Ọjọ Abamẹta to tẹle ni Joe ku.

Bawo ni igbe aye ṣe ri lẹyin ti Joe ku?

Mercy ni igbagbọ pe iku ọkọ rẹ, Joe, yoo mu ki ijọba wa nkan ṣe si ibudokọ omi Abonnema, lati sọọ di ibi to pojuowo, ti yoo si ni awọn adoola ẹmi, iwe akọsilẹ orukọ awọn arinrinajo, ati awọn eroja mi i.

O ni o yẹ ki awọn ọlọpaa oju omi wa ti yoo ma tọpinpin bi nkan ṣe n lọ, ati pe ki awọn alaṣẹ maa ko idọti oju omi naa, ko maa ba maa kọ ẹnjinni ọkọ oju omi, eyi to maa n fa ijamba.

Abilekọ Blankson ni, gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti ṣeleri lati pese iranlọwọ fun eto ẹkọ awọn ọmọ oun, ati lati fun oun ni iṣẹ nileeṣẹ ijọba.

Ẹwẹ, o ni yoo dara ti ilu Bakana ba ṣe nkan iranti kan si ibi ti ọkọ oun ku si, nitori ti awọn ọmọ rẹ ba n beere ibi ti wọn sin baba wọn si l'ọjọ iwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBimpe: Èèyàn bíi tiyín ni àfín, ẹ dẹ́kun dídẹ́yẹsí àfín

Related Topics