Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Adebayọ Salami, ti gbogbo eeyan mọ si Ọga Bello ti salaye fun BBC Yoruba pe, ko dara bawọn osere tiata se n ko ara wọn sita lori ẹrọ ayelujara pẹlu ija gbogbo igba.

Ọga Bello ni, aigbọn lo n da ọpọ wọn laamu, ti oun si maa n ba wọn da si aawọ naa nigba mii.

Amọ o ni ẹkọ ile ti wọn ba ni, ni yoo sọ bi wọn yoo se gba imọran oun si.

Ọga Bello tun tako ọrọ kan ti akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata, Yẹmi Solade sọ pe, alagbe ni ọpọ osere tiata.

Bello ni isẹ awọn ni awọn n se, ifẹ tawọn araalu ni sawọn, si n lo n jẹ ki wọn maa se aanu awọn.

O tun fi idi rẹ mulẹ pe, ajọsepọ to dan mọran wa laarin awọn osere ori itage to wa ninu ẹgbẹ ANTP ati Tapan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: