Akintọla Williams: Àwọn nkan tó ṣe pàtàkì tó yẹ kí o mọ̀ nípa Olùṣirò owó Àgbà àkọ́kọ́ ní Afrika

Akintọ̀la Williams ati Gomina Ambọde Image copyright Facebook /Lagos State Government
Àkọlé àwòrán Akintọla Williams ni Aarẹ akọkọ fun Institute of Chartered Accountants, ICAN

Olóyè Akintọla Williams ni Oluṣiro owo Agba akọkọ ni ilẹ Afrika, Chartered Accountant. O pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrun bayii.

 • Wọn bi oloye Akintọla Williams ni ọjọ kẹsan, oṣu Kẹjọ, ọdun 1919.
 • O lọ si ileewe alakọbẹrẹ Olowogbowo Methodist Primary School, Apọngbọn, nilu Eko ni nkan ni ọdun 1930, ko to di pe o lọ kawe nilu London.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒní ni ìrántí ọjọ́ tí Fẹla papòdà
 • Igba to pada de si orilẹede Naijiria ni 1950, o ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ to n pawo wọle fun ijọba, Inland Revenue titi di ọdun 1952. Lẹyin eyi lo da ileeṣẹ iṣiro owo ara rẹ, Akintọla Williams & Co. silẹ. Ileesẹ rẹ ọhun ni ileeṣẹ olusiro owo agba akọkọ to jẹ ti ọmọ Afrika nilẹ Afrika
 • O si sisẹ fun awọn ileeṣẹ bi ileeṣẹ iwe iroyin Nnamdi Azikiwe (The Pilot), Fawẹhinmi Furniture ati Ojukwu Transport. Bakan naa lo n gba iṣẹ lọdọ ileeṣẹ amunawa Naijiria, Electricity Corporation of Nigeria, Nigeria Railway Corporation ati Nigerian Ports Authority.
Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Akintọla Williams pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrun bayii.
 • Williams Akintọla ko ipa pataki ninu idasilẹ Ẹgbẹ awọn Oluṣiro owo ni Naijiria, Association of Accountants in Nigeria (AAN), l'ọdun 1960, pẹlu afojusun lati maa pese ẹkọṣẹ fun awọn oluṣiro owo. Oun naa ni Aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ naa.
 • Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ to bẹrẹ ile ẹkọṣẹ awọn oluṣiro owo agba, Institute of Chartered Accountants of Nigeria, ICAN, ohun naa ni Aarẹ akọkọ fun ile ẹkọ naa.
 • Ẹwẹ, o ko ipa to jọju ninu idasilẹ Ọja paṣi-paarọ ipin idokowo, Nigerian Stock Exchange, ni 1960. Oun nikan si lo ku laye ninu gbogbo awọn to fi ọwọ si iwe igbọraẹniye lori idasilẹ rẹ
Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Àwọn ènìyàn nlanla ló péjú sí ibi ayẹyẹ ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn Akintọla Williams
 • Alaga igbimọ to n riṣi gbigba owo ori fun ijọba apapọ laarin ọdun 1958 - 1968
 • Igbimọ oluwadi Coker Commission, to ṣe iwadi awọn awọn ileeṣẹ to jẹ ti ẹkun Western Region of Nigeria l'ọdun 1962
 • Ọmọ igbimọ majẹobajẹ fun ajọ Commonwealth Foundation laarin ọdun 1966-1975
 • O jẹ Alaga ajọ to ṣe atunṣe si kudiẹ-kudiẹ to wa ninu eto sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ti ajọ Udoji Salary Review Commission ṣe( 1975)
 • Oun naa ni oludasilẹ ati alaga igbimọ majẹobajẹ fun Ẹgbẹ awọn Akọrin ni Nigeria, MUSON.
 • Lẹyin to fẹhinti l'ọdun 1983, Akintọla Williams fi ara ji fun idasilẹ gbọngan fun iṣẹ orin kikọ ati ajọdun orin, MUSON Centre, to wa ni Onikan, nilu Eko
 • Ijọba Naijiria fi ami ẹyẹ Officer of the Order of the Federal Republic, O.F.R, da a lọla l'ọdun 1982.