Òsìsẹ́ ilé-wòsàn Ondo: Gbogbo ìgbà ni alárùn ọpọlọ ń kọlù wàá

Alarun ọpọlọ Image copyright Getty Images

Ọkunrin alarun ọpọlọ kan lu awọn oṣiṣẹ ileewosan ti wọn ti n tọju awọn alarun ọpọlọ ni alubami.

Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Akurẹ, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ naa la gbọ pe, o gbe ọkunrin alarun ọpọlọ naa lọ sileewosan nitori pe ọrọ rẹ ko baramu lasiko to jẹwọ fun awọn ọlọpa pe, oun wa lara awọn to pa Khadijat, ọmọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo nigba kan, Lasisi Olubọyọ.'

Ọkunrin ọhun, Fọlọrunsọ Olawale, ni iroyin naa sọ pe 'aisan rẹ le si’ nigba to de ileewosan naa, to si bẹrẹ si ni ba awọn irinṣẹ ileewosan jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Ati pe o lu awọn nọọsi, to fi mọ Ọga Agba nileewosan naa, Dokita Akinwumi Akinloye, ni alaubami.''

Eyi lo mu ki awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ṣe ifẹhonu han ni Ọjọbọ, lati fi ẹdun ọkan wọn han si ohun ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi 'aibikita ijọba ipinlẹ naa si alaafia wọn.'

Image copyright Getty Images

Awọn olufẹhonu han naa fi ẹsun kan pe, ijọba n fi ẹmi wọn wewu lọwọ awọn alarun ọpọlọ ti wọn ba gbe wa sileewosan naa, nitori pe gbogbo igba ni wọn maa n kọlu wọn.

Iha wo ni ẹgbẹ awọn osisẹ ile-wosan kọ si isẹlẹ yii ?

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn olutọju alaisan, Alaga Igbimọ to n duna-dura fun alekun owo osu nipinlẹ Ondo, to tun jẹ Alaga ẹgbẹ awọn Nọọsi nipinlẹ Ondo, Ọpẹyẹmi Oloniyo sọ fun BBC Yoruba pe, awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ti pada sẹnu iṣẹ wọn, ati pe ijiroro ṣi n lọ lọwọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan ijọba.

Nigba to n sọrọ lori aisi ipese awọn ohun eelo fun aabo lọwọ ikọlu, tawọn osisẹ ile-wosan naa n fẹhonu han le lori, Oloniyọ fi kun pe, diẹ-diẹ ni ijọba yoo maa pese awọn ohun eelo aabo nile iwosan nitori ilu Romu ko se kọ ni ọjọ kan soso.

Ijọba Ondo fesi si isẹlẹ yii.

Ẹwẹ, akòwé àgbà fún ìgbìmọ̀ ìlé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Ondo Dr Niran Ikumọla ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ẹgbẹ awọn nọọsi nipinlẹ Ondo ti ṣe 'wọde lẹyin ti alarun ọpọlọ kan lu nọọsi ati dokita to n tọju rẹ nilu Akure.

O fidi rẹ mulẹ nigba to ba BBC Yoruba sọrọ pe ijọba ko lẹbi kankan ninu iṣẹlẹ to ṣẹlẹ.

O rọ awọn nọọsi lati ba ijọba sọ ohunkohun ti o ba n dun wọn ni itubi-inubi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkọ̀wé àgbà ìgbìmọ̀ ilé ìwòsàn ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù ilé ìwòsàn àwọn alárùn ọpọlọ