CAN: Ìjọ tó bá bá àwọn èèyàn láramu ni kí wọ́n lọ̀

Ile ijọsin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán CAN ni ọrọ ọhun ku sọwọ awọn eeyan to ba n lọ sawọn ile ijọsin kọọkan

Ni ẹnu lọọ-lọọ yii, ariwo gee ti gba ori ikanni ayelujara lori bi awọn iranṣẹ Ọlọrun kan ṣe n pe fun 'eso owo' lati ọdọ awọn ọmọ ijọ wọn.

Ariwo iranṣẹ Ọlọrun kan lo kọkọ gba ori afẹfẹ kan, ninu fidio kan ti o ti npe fun awọn ọmọ ijọ ti yoo fi owo dọla ilẹ Amẹrika silẹ, gẹgẹ bii eso fun Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Lati ilẹ yii titi de oke okun ni ariwo ti lori isẹlẹ yii - bi awọn kan ṣe n ti wọn lẹyin pe ko si ohun to buru ninu rẹ, ni ọgọọrọ miran ti n pariwo pe Ọlọrun ko roro to bẹẹ.

Eruku ọrọ naa ko ti lọ silẹ, ti fidio kan tun jade bayii ninu eyi ti iranṣẹ Ọlọrun miran, ti n beere fun ilaji miliọnu kan naira lọwọ awọn akẹkọ gẹgẹ bii eso fun Ọlọrun.

eyi lo wa mu kawọn araalu maa beere pe se ilana gbigba eso owo nla-nla yii baa ofin Ọlọrun mu ?

Image copyright Getty Images

Amọ ṣa, ẹgbẹ CAN ni ọrọ ọhun ku sọwọ awọn eeyan to ba n lọ sawọn ile ijọsin kọọkan. Eyi ti o ba wu wọn ni wọn lee ṣe gẹgẹ bi o ba ṣe dara ninu ọkan wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ CAN ni awọn ko laṣẹ lati ba ẹnikẹni wi nitori Ajọṣepọ laarin awọn onigbagbọ ati ijọba lo jẹ awọn logun

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, olubadamọran fọrọ iroyin fun aarẹ apapọ ẹgbẹ CAN lorilẹede Naijiria, Ẹni-ọwọ Bayọ Oladeji ṣalaye pe, ko si ni ikawọ CAN lati sọ boya ijọ kan lẹtọ lati beere fun owo lọwọ ọmọ ijọ tabi rara.

"Ijọ ti ẹ ba ti n lọ to ba baa yin lara mu naa ni ki ẹ maa lọ. CAN ko lee sọ pe ẹ gbe owo eleyi kalẹ tabi ki ẹ maa gbe tọhun kalẹ.

Ẹgbẹ CAN ko laṣẹ lati ba ẹnikẹni wi tabi gbee soke. Ajọṣepọ laarin awọn onigbagbọ ati ijọba lo jẹ wa logun."