ASUP Ọ̀sun: Àjẹsíẹlẹ̀ owó oṣù méjìdínlógún ló mú wa wo isẹ́ níran

Ile ẹkọ giga gbogboun'se ipinlẹ Ọṣun
Àkọlé àwòrán Iyanṣẹlodi awọn olukọ nileẹkọ giga yii n waye lẹyin bi ọsẹ kan lẹyin ti awọn olukọ nileẹkọṣẹ olukọni ni ilu Ileṣa naa ti gun le iyanṣẹlodi

Ile ẹkọ giga mẹta nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti gbe ti pa bayii nitori iyanṣẹlodi awọn olukọ nibẹ.

Awọn olukọ labẹ aṣia ẹgbẹ olukọni ileẹkọ giga gbogbonise lorilẹede Naijiria, ASUP lawọn ileẹkọ giga gbogboniṣe nipinlẹ Ọṣun gunle iyanṣẹlodi naa lati fi ẹhonu han lori aisan owo oṣu mejidinlogun ti ijọba jẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

Awọn ileẹkọ giga ti ọrọ kan ni ile ẹkọ giga gbogbonse Poly ipinlẹ Ọṣun ni ilu Iree, ileẹkọ giga imọ ẹrọ ni ilu Ẹsa oke ati ile ẹkọṣẹ olukọni to wa nilu Ila Ọrangun.

Iyanṣẹlodi awọn olukọ nileẹkọ giga yii n waye lẹyin bi ọsẹ kan ti awọn olukọ nileẹkọṣẹ olukọni ni ilu Ileṣa naa ti gu le iyanṣẹlodi.

Àkọlé àwòrán Amọ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ni awọn ko tii gbọ nipa iyanṣẹlodi kankan.

Lẹyin ipade gbogbogbo ti wọn ṣe lọgba ile ẹkọ giga gbogboun'se ipinlẹ Ọṣun ni ilu Iree, agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn olukọni ile ẹkọ giga gbogboun'se lorilẹede naijiria, ASUP lawọn ileewe naa, Ọmọwe Jacob Adegbite ni igbesẹ awọn olukọni ọhunda lori ẹhonu wọn.

Awọn olukọni ile ẹkọ giga gbogbo-nse Poly naa n beere fun sisan ẹkunrẹrẹ ajẹẹlẹ owo oṣu wọn fun oṣu mejidinlogun ati gbogbo adehun to wa laarin awọn ati ijọba.

Amọ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ni awọn ko tii gbọ nipa iyanṣẹlodi kankan.

Kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Lani Baderinwa ni 'ijọba gomina Aregbeṣọla ko lee yẹ ipinnu rẹ lori alaafia awọn oṣiṣẹ'