Sunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Sunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Olùdásílẹ̀ ìjọ Embassy of God ní orílẹ̀-èdè Ukraine, Olùsọ́-àgùtàn Sunday Sunkanmi Adelaja, lasiko to n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ni, òwò sise ni awọn pasitọ kan ni orilẹ-ede Naijiria n se, pẹlu bi wọn se n beere owo lọwọ awọn ọmọ ijọ wọn ki wọn lee di olowo tabi se rere laye.

Adelaja ni, owo ti awọn pasitọ naa n gba bii owo irugbin ‘Seed’, ko ba ofin Ọlọrun mu, owo ọrẹ nikan ni Ọlọrun fi ọwọ si.

O fikun pe, atinuda gan ni idamẹwa jẹ, tori ofin majẹmu laelae ni, ko si ninu majẹmu tuntun, ti Jesu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ko si gba idamẹwa ri nigba aye wọn.

Oludasilẹ ijọ Embassy of God naa tun ni, ẹni to ba wu lee da idamẹwa, ida kan, meji abi ida ọgbọn, lai jẹ pe ẹnikẹni sọ iye ti yoo da fun Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: