Ọsẹ́ tí òògùn Tramadol ń se lára
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Dókítà Òbílàdé: Ẹni tó bá lo Tramadol lálòjù leè sùn, kó má jí mọ́

Ninu ifọrọwerọ pẹlu Onisegun Oyinbo kan pẹlu BBC Yoruba, Dokita, Kunle Obilade ni iwọnba oogun Tramadol lee din ara riro ku, amọ aloju rẹ lewu pupọ.

Nigba to n sọrọ lori afurasi ajinigbe kan to ti n sun fun ọjọ mẹfa lai laju nipinlẹ Ondo nitori oogun Tramadol to mu, Obilade ni to ba jẹ pe wọn tete gbe afurasi naa lọ si ile iwosan, o seese ki wọ́n fa oogun naa kuro lara rẹ, amọ niba yii to ti dapọ mọ ẹjẹ rẹ, boya ni ko fi ni se ipalara fun ẹmi rẹ.

Dokita naa tun la mọlẹ pe, aloju oogun Tramadol maa n ge ẹmi kuru ni.