Technovation 2018: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́-binrin Naijiria gba ipò kínní

Aworan Save-A-Soul Image copyright @technovation
Àkọlé àwòrán Áwọn akẹkọ obìnrin Nàìjíríà naa gbogbo Naijiria ga nínú ìdíje ìmọ ẹrọ l'amerika

Ikọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kan to soju orileede Nàìjíríà ti ṣe bẹ fagba han orílèèdè Amerika, Spain,Turkey, Uzbekistan ati China lati gba ami ẹyẹ ipele àwọn ojẹ-wẹwẹ, nínú ìdíje ìmọ ẹrọ ''Technovation World pitch'' tọdun 2018, to waye nilu San Francisco, ni orilẹ-ede Amerika.

Ikọ naa, ti orukọ rẹ n jẹ ''Save-A-Soul'', se agbekalẹ imọ ẹrọ ayelujara kan, ‘app’ lori ẹrọ̀ alagbeka, ti wọn pe orukọ rẹ ni ''FD Detector''.

'App' naa n sisẹ lati dẹkun itankalẹ ayederu oogun oloro lorileede wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Wọn ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samu-samu. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́-binrin Naijiria òhun, lo gba ipò kínní láàrin ẹgbàá oludije tó ṣe àfihàn iṣẹ ọwọ wọn níbi ìdíje náà.

Awọn akẹkọ obinrin naa, yoo gbinyanju lati ta ‘app’ wọn fun awọn oludokowo ni Silicon Valley nilu California.

Ojo ikinni ti n rọ sori awọn akẹkọ-binrin naa

Yooba ni bi eegun ẹni ba jo ree, ori a maa ya atọkun rẹ. Aseyori awọn ọmọ obirin naa, ti mu ikinni ku orire wa lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria atawọn asaaju wa.

Koda Adele Aarẹ, Yemi Osinbajo ati Aarẹ ile asofin agba, Bukola Saraki naa kan saara si wọn.

Wọn se agbekalẹ idije ''Technovation'', lati gba awọn ọmọ obinrin ni iyanju ki wọn baa le se oun eelo to le mu igbayegbadun ba awujọ wọn.

Image copyright edufuntechniknig
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba akọkọ ti ikọ oludije ọjẹwẹwẹ Naijiria kankan yoo di abala asekagba idije naa .

Gegẹ bi ohun ti ikọ Save-A-Soul sọ, orileede Naijiria laaye ti gba tita oogun ayederu ju lọ.

Awọn akẹkọ naa to wa lati ipinlẹ Anambra, ni ila oorun guusu orileede Naijiria sọ pe, awọn fẹ pawọpọ pẹlu ajo to n moju to isakoso ounje ati ogun lorileede Naijiria NAFDAC, ki wọn ba le koju ipenija ayederu ogun.

Lalẹ ọjọbọ ni wọn gba ami ẹyẹ naa lẹyin ti awọn adajọ eto kaakiri agbanlaaye se ayẹwo isẹ wọn.