Àtundi ìbò Katsina: APC ri Sẹnẹtọ túntún kúnrá nílé Asojú-sòfin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ahmad Babba Kaita
Ahmad Babba Kaita yoo jọwọ ipo rẹ nile asojusofin lati di ọmọ ile asofin agba
Ọrọ náà jọ bí eré ṣugbọn kii se ere. Abúrò kan ree ti ko mọ agba lẹgbọn nínú atundi ìdìbò to waye nipinlẹ Katsina.
Ahmad Babba Kaita, ti ẹgbẹ òṣèlú APC lo pegede nínú ìdìbò náà eleyi ti oun ati ẹgbọn rẹ, Kabir Babba Kaita ti ẹgbẹ òṣèlú PDP jijo kojú.
Nínú Iransẹ ìkínni lójú òpó Twitter rẹ, ẹgbẹ òṣèlú APC ki Kabir ku oriire àṣeyọrí rẹ nínú ìdìbò òhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò fẹ́ eégún onídọ̀tí ní ààfin mi - Oluwo
- Oshiomọlẹ ń se bi adìẹ tí ojò pa, tó ń sunkún kiri- Saraki
- "Ohun tí ojú opó ń rí láwùjọ kò kéré"
- Tanka epo tó jóná gbẹ̀mí àdájọ́, ọmọkùnrin rẹ àtàwọn míì
- Sé ó yẹ kàwọn pásítọ̀ máa bèèrè èso owó ńlá-ńlá ?
- Alárùn ọpọlọ lu àwọn nọ́ọ̀sì àti dókítà agba níléèwòsàn ní àlùdákú
- Irú ẹ̀dá wo ni aṣòfin Bukola Saraki jẹ́?
Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú
Gẹgẹ bí òhun tí wọn fi síta, Ahmad fi ìbò 224,607 tayọ ẹgbọn rẹ, Kabir, tó ní ìbò 59,724.
Ni báyìí, Ahmad Babba ní yóò jẹ Seneto ti yóò maa sójú ẹkùn àríwá Katsina nile aṣòfin àgbà lorílè-èdè Nàìjíríà.
Anfààní nla ní iyansipo rẹ yóò jẹ fún ẹgbẹ òṣèlú APC pẹlú bí àwọn Seneto kan ṣé fi egbe náà silẹ lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP laipẹ yìí.