Ọlọ́pàá: À ó wá agbẹ́bọn tó pa ọmọ ikọ IRT mẹ́rin

Awọn osisẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE/IRT

Àkọlé àwòrán,

Mẹ́ta ninu awọn ọlọpaa mẹrin to padanu ẹmi wọn

Kowee ke ko ha ni abule Jankasa, nijọba ibilẹ Rigasa nipinlẹ Kaduna, ni aago mẹfa abọ irọlẹ ọjọ abamẹta, nigba ti awọn gende agbebn dena de awọn ọlọpaa kan to wa lẹnu isẹ wọn ni abule naa.

Lẹyin ija ajaku akata pẹlu ibọn ti wọn fi sere ọwọ, mẹrin ninu awọn ọlọpaa naa dero ọrun, ti wọn ko si tii ri ọkankan ninu awọn janduku ẹda naa mu.

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa ti waye fawọn akọroyin, Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Sabo Yakubu ni, laipẹ-laijinna ni ọwọ yoo tẹ awọn agbegbọn to da iwa naa ni asa, ti wọn yoo si fi imu wọn ko ata ofin.

Adari ikọ IRT ti ileeṣe ọlọpaa, Abba Kyari, ṣalaye pe bi ikọ̀ òun ṣe ń jáde láti inú igbó ni àwọn akẹgbẹ́ awọn ajínigbé ti awọn ti mú dà'bọn bò wọ́n.

Awọn ọlọpàá tó kú ninu iṣẹlẹ naa ni Benard Odibo, Mamman Abubakar, Haruna Ibrahim ati Emmanuel Istifanus.

Kyari sọ pe wọn ti gbe oku wọn lọ mọṣuari kan ni Ipinlẹ Kaduna, ati pe iṣẹ n lọ lati wa awọn agbebọn naa ri

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

'Ọ̀lọ́wọ́ òsì kọ́ndọ́rọ́'

Sabo wa n kesi awọn araalu, to ba ni iroyin lọwọ, lori bi wọn se lee ri awọn afurasi ọdaran to sisẹ laabi naa mu, lati tete fi iroyin ọhun sọwọ si ileesẹ ọlọpaa.