River Nile: Ọmọ ilé-ìwé Kenba 24 ló kú s'ómi ní Sudan

River Nile
Àkọlé àwòrán Afi ki ọlọrun ma jẹ ki abiyamọ fojú sunkun ọmọ.

Afi ki ọlọrun ma jẹ ki abiyamọ fojú sunkun ọmọ.

Sùgbọn ni ti àwọn obí ọmọ mẹrinlélógun ile -iwe Kenba High School to padanu ẹmi wọn ni orilẹ-èdè Sudan ni ko ri bẹẹ fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìṣẹlẹ ọ̀hún ló waye ní ìhà ariwa Sudan lasiko ti awọn ọmọ náà ń lọ si ile ẹkọ wọn, wọn ni ojiji ni ẹnjini bajẹ ti ọkọ oju omi náà si bẹ̀rẹ̀ si ni ri.

Yatọ si àwọn ọmọ wọnyìí ninu ọkọ àwọn oṣiṣẹ eto ilera náà wa nínú ọkọ ti wọn si bomilọ

Àkọlé àwòrán Oku ọmọ meji pere ni wọn

Wọn ni ogoji ọmọ lo wa ninu ọkọ oju omi to rì náà sugbọn ti ori ko àwọn to ku yọ lágbegbe odo Nile.

Ọmọ ọdun meje si mẹrindinlogun ní àwọn ọmọ to wa ninu ọkọ náà gẹgẹ bii ọga agba ile-iwe náá, Ab el-Khayr Adam Yunis, ṣe sọ fun BBC àti pe ẹru lo ba awọn ọmọ náà nigba ti ẹngini sọsẹ silẹ ti gbogbo wọn si wọ jọ soju kan èyi to faa ti ọkọ oju omi náà fi doju de.

Oku ọmọ meji pere ni wọn ṣi rí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà