'Ilé orin wa tí Ajimobi tun kọ́ dára púpọ̀, ṣùgbọ́n a kò ní dẹ́kun òtítọ́'

Ayefele

Oríṣun àwòrán, @yinkaayefele

Àkọlé àwòrán,

Ayefele

Lẹyin oṣu mẹta ti Ijọba Ipinlẹ Oyo wo ileeṣẹ orin Yinka Ayefele to wa ni agbegbe Challenge, Ibadan, o ti dupẹ lọ́wọ́ Gomina Ipinlẹ naa, Abiola Ajimọbi, bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko ni dẹkun lati maa sọ ootọ ọrọ to maa ṣe ara ilu lanfani.

O sọ fun BBC Yoruba pe eyi ti ijọba kọ wayi tilẹ̀ dara ju ti eyi ti wọn wo lọ.

Àkọlé fídíò,

Ilé orin wa tí Ajimobi tun kọ́ dára púpọ̀, ṣùgbọ́n a kò ní dẹ́kun òtítọ́

Ẹ o ranti wi pe oṣu kẹjọ ni Ipinlẹ Oyo wo ileeṣẹ orin naa latari pe ko gba iwe to tọ. Igbesẹ naa bi awọn ara ilu ninu gidi.

Ṣugbọn Ayefele ni oun ko ba ijọba ja, bẹẹ ni oun ki i ṣe ọta Ajimọbi.

Oríṣun àwòrán, David Ajiboye

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni 'aigbọran Yinka Ayefẹlẹ lo mu ki awọn wo ileeṣẹ rẹ.'

Látàrí ìlérí tí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ti ṣe láti wá ǹkan ṣe sí ilé iṣẹ́ rẹ́díoò Yinka Ayefẹlẹ tí wọ́n wó, ó ti ṣèpàdé pẹ̀lú olórin náà.

Níbi ìpàdé àtilẹ̀kùnmọ́rí ṣe ọ̀hún, àwọn lọ́ba lọ́ba wà níbẹ̀ tó fi mọ́ olùgbani nímọ̀ràn àgbà fún gómìnà lórí ìṣe dára dára, ọ̀mọ̀wé Isaac Ayandele.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn lọ́ba lọ́ba náà bá wọ́n pé níbi ìpàdé náà

Ẹ̀wẹ̀, ní àkókò tí ikọ̀ oníròyìn wa kó ìròyìn yìí jọ, a kò tíì mọ àbájáde ìpàdé náà.

Àkọlé fídíò,

Ajimọbi: Pé Ayefẹlẹ jẹ́ àkàndá kò fún láṣẹ láti rú òfin

Kò sẹ́ni tó tayọ òfin

Ṣáájú àkókò yìí, gomina ipinlẹ Ọyọ Abiọla Ajimọbi ti sọ ninu fọnran awọran tó wà loke yii pe oun yoo wa nnkan ṣe si ọrọ ileeṣẹ Fresh Fm, to jẹ ti gbaju-gbaja onkọrin Yinka Ayefẹlẹ, eleyi to ti di orisun awuyewuye bayii lẹyin ti ijọba wo ile naa ni owurọ ọjọ aiku.

Ninu ọrọ kan to ba awọn akọroyin sọ lẹyin to kirun ọdun ileya tan ni yidi Agodi nilu Ibadan, ni gomina Ajimọbi ti sọ ọrọ yii.

O ni ko si ẹni to tayọ ofin bi o ti wu ki ipo ti ẹni bẹẹ ba wa ṣe lee ri lawujọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìgbé ayé Instagram fún ọ́sẹ̀ kan

Gomina Ajimọbi ni, ni iwoye ti oun, ibi ti ileeṣẹ Ayefẹlẹ wa ko ba ofin mu ati pe, awawi ni ohun ti awọn kan n sọ kiri pe akanda ẹda ni, to si n gba ọpọlọpọ eeyan siṣẹ.

"Ṣe awọn adigunjale naa ko gba eeyan siṣẹ ni ? Abi ka sọ pe tori pe wọn gba awọn eeyan si ẹnu iṣẹ, ka fi wọn silẹ."

Ayefẹlẹ: Orí ìkúnlẹ̀ ni ìyàwó mi wà, tó ń bẹ gómìnà, láti 11pm si 4am

Àkọlé fídíò,

Ayefẹlẹ: Orí ìkúnlẹ̀ ni ìyàwó mi wà, tó ń bẹ gómìnà, láti 11pm si 4am

Fidio oke yii lo n salaye ipade akọroyin ọtọọtọ, ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ati Yinka Ayefẹlẹ se lori ileesẹ Fresh FM ti ijọba wo lulẹ lọjọ Aiku, amọ ti alaye igun kọọkan lori isẹlẹ naa tako ara wọn

Ohun tó wà lórí ilẹ̀ Ayefẹlẹ́ ju àsẹ tó gbà lọ - Ìjọba Ọ̀yọ́ .

Wayi o, Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣe alaye wipe, eti ikun ti gbaju-gbaja akọrin juju, Yinka Ayefẹlẹ kọ si aṣe ajọ to n risi aato ati idagbasoke ilu, lo mu ki ijọba wo apa kan ile iṣẹ redio rẹ.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi ipade akọroyin naa, Adedayọ Okedare jábọ̀ pe, adari ajọ to n risi aato ati idagbasoke ilu nipinlẹ Ọyọ, Waheed Gbadamọsi lo ṣe alaye ọrọ ọhun, nibi ipade awọn akọroyin to waye nile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyo l'ọjọ Aje.

Gbadamọsi ni "awọn ile iṣẹ igbohun safẹfẹ mejilelogun ọtọọtọ ni ijọba kesi, lati ṣe afihan iwe aṣẹ ti wọn fi kọ ile iṣẹ wọn ninu osu Kaarun ọdun 2017.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ni ile iṣẹ naa ko lẹtọ lati kọ apa ibi ti ijọba wo, lai ṣe ohun ti ijọba fẹ.

Ati pe iṣẹ iwadi ati abẹwo ti awọn asoju ijọba ṣe si ile iṣẹ redio Ayefẹlẹ, lo fi idi ọrọ mulẹ wipe gbajugbaja olorin naa ti tayọ aṣẹ ti ijọba fun un."

Ijọba fi ẹsun kan pe, yatọ si ojupopo ti ile iṣẹ naa bọsi, to si n ṣe fa ijamba ọkọ ni agbegbe naa, ile igbọnsẹ, yara idana, gbọngan igbalejo ati pẹtẹsi to n bẹ lẹyin ile naa, tako aṣẹ ti ijọba buwọlu.

O fikun ọrọ rẹ wipe, lati inu osu kẹfa ọdun 2017 niwọn ti kọwe si Ayefele lati wa se atunṣe, sugbọn o kọ eti ọgboin sijọba.O ni ile iṣẹ naa ko lẹtọ lati kọ apa ibi ti ijọba wo, lai ṣe ohun ti ijọba fẹ.

Àwíjàre iléèṣẹ́ Fresh FM lórí àwọn ẹ̀sùn nàá

"Ohun elo igbohun safẹfẹ ti owo rẹ ko din ni milliọnu mejidinlọgbọn naira lo da wo lasiko ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi katakata wo ile iṣe redio Fresh Fm ti o jẹ ti gbajugbaja akorin juju, Yinka Ayefẹlẹ lojo Aiku."

Adari ipolongo fun ile iṣe redio naa, David Ajiboye lo sọ ọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ninu ọgba ile iṣẹ naa to wa ni opopona Challenge, Ibadan.

Ajiboye bẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Ọyọ pẹlu ẹsun wipe igbese naa lọwọ oṣelu ninu.O ni ọjọ Aje, ogunjọ osu Kẹjọ lo yẹ ki awọn aṣoju ile iṣẹ redio naa ati ijọba ipinlẹ Ọyọ jọ pade nile ẹjọ giga kan nilu Ibadan lori ọrọ ọhun, sugbọn ìjọba ipinlẹ Ọyọ ko duro de asiko ti ile ẹjọ da ki o to ṣe ifẹ inu rẹ.

Àkọlé àwòrán,

Ajiboye bẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Ọyọ pẹlu ẹsun wipe igbese naa lọwọ oṣelu ninu.

Ọrọ yi ni ọwọ oṣelu ninu, a si mọ wipe kọmiṣọna fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun lo wa nidi ẹ nitori lọpọlọpọ igba lo ti pe wa wipe ki a paarọ awọn eto wa kan nitori wọn n tako ijọba.A si sọ fun-un wipe ile iṣẹ olominira le yi.

Awọn ile iṣẹ igbohun safẹfẹ ti o jẹ ti ijọba ni wọn le paṣẹ fun."Ajiboye tẹsiwaju wipe aifi aye silẹ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ lati tọwọ bọ eto ile iṣẹ redio naa loṣokunfa igbeṣe ati lo ọwọ agbara.O se afikun ọrọ wipe ile iṣẹ redio naa yoo duro de idajo ile ẹjọ lori ọrọ ọhun.

Ìdí ti gómìnà Ajimobi fi wo ilé mi- Ayefelẹ

Oludasilẹ ileesẹ Fresh Fm, Yinka Ayefẹlẹ ti fesi si bi ijọba ipinlẹ Ọyọ se wo ileesẹ redio naa ni kutu hai aarọ ọjọ Aiku.

Yinka Ayefẹlẹ, lasiko to n sọrọ lori redio ọhun, Fresh FM, to bẹrẹ isẹ pada lẹyin wakatai meji ti ijọba wo ile naa, rọ awọn araalu to n se atilẹyin fun-un, lati mase da rogbodiyan kankan silẹ lori isẹlẹ naa.

O tun dupẹ lọwọ gbogbo agbaye fun atilẹyin wọn pẹlu afikun pe ibi to ba le, la n ba ọmọkunrin.

"Ẹ ni suuru, ẹma fa rogbodiyan, to ba jẹ pe lootọ lẹ́ ni ifẹ́ mi, mo bẹ yin ni, ẹ mase jo ọkọ ijọba to wa nilẹ.

Bi ijọba tilẹ wo ileesẹ, redio Fresh FM ko lee wo lailai, tori araalu lo nii."

"Bakan naa ni Ayefẹlẹ tun dupẹ́ pupọ lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ fun ibi ti wọn sin oun de, o si tun dupẹ lọwọ kọmisana f'eto iroyin, Toye Arulogun, pe oun lo pilẹ ọrọ bi wọn yoo se wo ile oun, oun si ki pe o ku aseyọri lori isẹ naa.

Igbimọ ọdọ Yoruba koro oju si bi ijọba Ọyọ se wo redio Ayefẹlẹ

Igbimọ awọn ọdọ nilẹ Yoruba ti koro oju si igbesẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ lori ileesẹ redio Yinka Ayefẹlẹ, Fresh FM.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Arẹmọ Ọladọtun Hazzan fi ọwọsi lọjọ Aiku, ẹgbẹ naa ni, isẹlẹ naa jẹ iwa aṣilo agbara, ọtẹ oselu ati titẹ ẹtọ ẹni loju, nitori pe o yẹ ki ijọba duro de idajọ ileejọ na, ko to lọ wo ileesẹ redio naa.

"Awa ọdọ nilẹ Yoruba n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ijọba gomina Abiọla Ajimọbi tipinlẹ Ọyọ gbe lati wo ileesẹ redio Fresh Fm, eyi to si lewu fun alaafia orilẹ-ede yii.

A wa n kesi ileesẹ aarẹ, ile asofin apapọ, adajọ agba lorilẹ-ede yii ati gbogbo ọmọ Yoruba pata-pata, pe ki wọn tete yọ suti ete si iwa bayii ko to bọwọ sori.

Awọn eekan ilu n lọ wo ileesẹ redio Ayefẹlẹ tijọba wo

Awọn eeyan ya kẹti-kẹti lọ si ileesẹ redio Fresh FM lẹyin ti ijọba wo ile naa.

Lara wọn ni ọkan ninu awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ l'abẹ ẹgbẹ oselu PDP, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde.

Oríṣun àwòrán, David Ajiboye

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni 'aigbọran Yinka Ayefẹlẹ lo mu ki awọn wo ileeṣẹ rẹ.'

O ni "Ni aye ọlaju ati ijọba tiwa-n-tiwa ta n se yii, iru igbesẹ wiwo ile bayii ko bojumu rara."

Ṣaaju iṣẹlẹ naa ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Rasheed Ladọja ati Engr Seyi Makinde parọwa sijọba ipinlẹ Ọyọ ninu atẹjade ọtọọtọ, lati mase wo ileesẹ redio naa, .

Bakan naa niasọfin lati nipinlẹ Ọyọ, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC to n tukọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lọwọ, Dapọ Lam-Adesina, naa wa sibi iṣẹlẹ naa, to si ni 'iwa ika bẹ ẹ ko dara rara.'

Dapọ Lam Adesina ni, o yẹ ki ijọba ipinlẹ Ọyọ duro de idajọ ileẹjọ ko to lọ̀ da ileesẹ redio naa wo niwọn igba ti ọrọ naa ti wa niwaju ileẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Olusina Olabode

Ijọba Ọyọ mu ipinnu wiwo ileesẹ redio Ayefẹlẹ sẹ

Lẹyin ọpọlọpọ awuye-wuye to ti waye lori iwe kan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi sita pe, oun yoo wo ileesẹ redio Fresh Fm, ti gbaju-gbaja olorin juju n ni, Yinka Ayefẹlẹ da silẹ, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti mu ipinnu rẹ sẹ, to si ti bi ile naa wo.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi isẹlẹ naa ni, deede aago mẹrin aarọ ọjọ Aiku ni awọn ẹrọ kata-kata ijọba ipinlẹ Ọyọ de si adugbo Challenge, nilu Ibadan ti ileesẹ naa wa, ti wọn si wo lulẹ.

Ọpọ eeyan ti ara aje n ta, lo n gbarata lori igbesẹ ijọba naa, tawọn eeyan miran si n bu sẹkun nibẹ.

A gbọ pe lasiko ti wọn fẹ bẹrẹ si gbe eto safẹfẹ lori redio Fresh FM ni isẹlẹ naa waye, ti wọn si tete ti ileesẹ redio naa pa.

Kíló pilẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwó ilé nàá?

Oríṣun àwòrán, @yinkaayefele/@tolanialli

Àkọlé àwòrán,

Yinka Ayefẹlẹ ní àwọn olóṣèlú ló ní kí Gómìnà Ajimọbi wó iléèṣẹ́ rédíò òun

Gbajugbaja olorin ni, Yinka Ayefẹlẹ ni kọmisana fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun lo wa nidi bi ijọba ṣe fẹ ẹ wo ileeṣẹ igbohun s'afẹfẹ oun, Fresh FM, to wa nilu Ibadan.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Ayefẹlẹ ni oun gba awọn iwe to yẹ ki oun to kọ ile naa. Ati pe ara ijọba ipinlẹ Ọyọ kọ otitọ ọrọ ni wọn ṣe fẹ gbe igbesẹ naa.

O fi ẹsun kan kọmisana naa pe o sọ̀ fun ileeṣẹ redio naa lati da awọn eto kan 'to n tọka si awọn nkan ti ko dara ninu eto iṣakoso ijọba Gomina Abiola Ajimọbi.

Yinka Ayefẹlẹ ni awọn ololufẹ ileeṣẹ igbohun s'afẹfẹ Fresh FM, to jẹ agbẹjọro ti gbe ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ s'ile ẹjọ.

Ẹkunrẹrẹ ọ̀rọ̀ rẹ n bẹ ninu fọnran yii:

Àkọlé fídíò,

Ayefẹlẹ - Ara ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kọ òtítọ́ ní wọ́n ṣe fẹ́ wó iléèṣẹ́ rédíò mi

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ ni ijọba kọ lẹta si ileeṣẹ redio Fresh FM pe ko 'gbe ile naa kuro nibi to wa laarin ọjọ mẹta, bi bẹ ẹ kọ, wọn yoo wo ni.

Ọjọ mẹta naa ti tẹnubodo lọjọ kẹẹdogun.

Sugbọn nigba ti a kan si kọmisana fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Toye Arulogun, ti Yinka Ayefẹlẹ fi ẹsun kan pe oun lo wa nidi iṣẹlẹ naa, Arulogun ni 'ti wọn ba sọ pe oun ni, oun naa ni.'

Oríṣun àwòrán, Toye Arulogun Snr/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ayefẹlẹ ko sọ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ̀ pe oun yoo lo 'Music House' fun ileeṣẹ redio nigba to fẹ gba iwe aṣẹ lati kọ ọ

Ati pe ki i se nkan ti Yinka Ayefẹlẹ sọ pe oun fẹ fi ile naa ṣe nigba to fẹ ẹ gba iwe aṣẹ lo fi ṣe. O ni ko si adehun redio ninu adehun to ba ijọba ṣe.

Ẹwẹ, Kọmisọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Ọyọ, Oloye Isaac Ishọla ni ko ni nkankan ṣe pẹlu Yinka Ayefẹlẹ, bi ko ṣe ofin ijọba to sọpe ẹni to ba fẹ ẹ k'ọle gbọdọ fi alafo amita marunlelogoji silẹ si oju popo. Ahesọ nipe tori wọn n sọrọ sijọba ni. Ibi ti wọn kọ ile naa si ko ba ofin mu.

O ni 'bi ẹẹmẹta nijọba ti kọ lẹta si i, sugbọn ti wọn ko dahun. Ati pe ile naa n fa ijamba.

Eniyan to ti padanu ẹmi wọn lati bi oṣu mẹsan nitori ibi ti ile naa wa , koda osisẹ wọn kan naa jana mọ mọto lẹnu.'