Kofi Annan: Ọbasanjọ àti Saraki nàá bá wọn péjú síbi ìsìnkú

Kofi Annan
Àkọlé àwòrán,

Kofi Annan

O darinako, odi oju ala.

Lẹyin ayẹyẹ isinku to waye lorileede Ghana l'Ọjọbọ,wọn ti sin oku akọwe ajọ isọkan agbaye nigba kan ri, Kofi Annan.

Awọn to wa nibi isinku naa ni titi lai , awọn ko ni gbagbe ipa ti Kofi Annan ko.

Jakejado agbalaaye lawọn àalejo ti wa lati ba ẹbi Annan kẹdun ipapoda rẹ.

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI/AFP/Getty Images

Nínú wọn là ti ri Ààrẹ orílèèdè Naijiria nigba kan ri Olusegun Obasanjo,Aarẹ ologun Naijiria tẹlẹ ri Ajagunfẹyinti Abdulsalam Abubakar àti akọwe apapọ àjọ iṣọkan orílèèdè àgbáyé Antonio Gutierrez.

Oríṣun àwòrán, Facebook/bukola.saraki

Senatọ Bukọla Saraki to jẹ Aarẹ ile asofin agba Naijiria naa pẹlu iyawo rẹ, Toyin Saraki naa pejọ sibi ẹyẹ ikẹyin fun Kofi Annan.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/bukola.saraki

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Fọ́fọ́ ni gbọ̀ngàn Accra International Conference Center kún fún èèrò láti dágbere fún Kofi annan

Oríṣun àwòrán, AFP

Orin ìyìn àti ọrọ àyọkà lorisirisi ni o wáyé níbi ètò ìsìnkú náà nibi ti ìbátan Akọwe àgbà nígbà kan rí náà, Kojo Amoo Gottfried ka ọrọ ìrántí nipa Kofi Annan.

Àkọlé àwòrán,

Awọn lọbalọba ni ilu Ghana naa jade wa lati wa se ẹyẹ ikẹyin fun Annan

Nínú rẹ lọ ti ṣe àpèjúwe bí Annan ti ṣe darí ifehonuhan kàn lati tako bi wọn ti ṣe n fún àwọn akẹkòó ni oúnjẹ tí kò sunwọ̀n nigba ti ọ wá ni ilé ẹkọ gírámà Mfantsinin ni ilu Accra.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Tìlù-tìfọn ni wọ́n fi sin Annan lọ s'ọ́run

Nínú awọn míràn to sọ ọrọ ìwúrí ni ìyàwó Annan,Nane Maria Annan ati awọn mọlebi rẹ míràn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n ti kọ́kọ́ tẹ́ Annan ní ìtẹ́ ẹ̀yẹ lẹ́yìn tí òkú rẹ̀ gúnlẹ̀ sí orílẹ̀èdè Ghana láti Switzerland

Iyawo rẹ ni kò si ìgbà tí Annan ba n pada wá sí ilẹ tí inú rẹ kìí dùn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Iyawo Koffi Annan, Nane wa lẹgbẹ rẹ̀ nigba to dagbere faye

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn oju opo ikan sira ẹni kun pitimu fun oniruuru idaro lati ẹnu awọn eekan ilu lagbaye.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter, Aarẹ Muhammadu Buhari daro pẹlu awọn ẹbi Kofi Annan lorukọ awọn ọmọ Naijiria.

Buhari ni iwa irẹlẹ ati ifẹ fun agbega ọmọniyan lo mu ki Kofi Annan tayọ lagbaye.

Ninu idaro tiẹ, olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May, ni iku Annan ka oun lara pupọ, asaaju to dantọ, ati olurapada ajọ isọkan orilẹ-ede agbaye, ẹni to ko ipa ribi-ribi lati mu ki aye dun gbe ju bo se baa lọ.

Tun wẹ, aarẹ orilẹ-ede Faranse, Emmanuel Macron naa daro ẹni re to lọ. O ni lojiji ni Annan faye silẹ lai dagbere.

Macron ni gbogbo agbaye ko ni gbagbe iwa pẹlẹ ati oju akin to ni.

Ninu atẹjade kan, Aarẹ orilẹede Ghana, Aarẹ Akufo-Addo fọwọsi, o ni iku oloogbe naa ba oun ati iyawo oun, Rebecca ni ojiji.

O se apejuwe Annan gẹgẹ bii ẹni to jẹ asoju rere fun orilẹ-ede Ghana lawujọ agbaye.

Oríṣun àwòrán, AFP

Gẹgẹ bi ajọ alaanu kan to da sile ti wi, "wọọrọ-wọ ni iku mu Kofi Annan lọ lasiko aisan ranpẹ to see àti pe ilumọka ni lagbaye, nitori o ja fita-fita ni gbogbo ọjọ aye rẹ fun ipese alaafia jake-jado agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ naa ni "Ti aini kan ba wa, o maa n na ọwọ sita lai tii kan sawọn eeyan pẹlu oju aanu ati iyọnu nla. O maa n fi awọn eeyan miran siwaju ara rẹ,o ni ikonimọra ati ọpọlọ pipe ninu ohunkohun to ba dawọle."

Kofi Annan, tii se ọmọ bibi ilẹ Ghana, lo n gbe orilẹ-ede Geneva fun ọjọ pipẹ, nibi ti ọlọjọ ti de baa.

Annan ti gba ami ẹyẹ olufẹ alaafia lọdun 2001 lori awọn akanse isẹ aanu to ti gbe se nigba aye rẹ ati bo se ta ajọ United Nations ji pada.

Oríṣun àwòrán, @theresa_may

Annan ni adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí yóò jẹ àkọ̀wé àpapọ̀ fájọ isọkan orilẹ-ede agbaye, United Nations, to si wa ni ipo naa fun saa meji ọtọọtyọ̀, eyiun ni aarin ọdun 1997 si 2006.

Lẹyin naa lo sisẹ gẹgẹ bii asoju ajọ isọkan agbaye si orilẹ-ede Syria, to si siwaju ikọ apẹtu-saawọ to lọ yanju ija ni Syria.

Asiko ti Annan wa lori oye bii akọwe agba ajọ isọkan agbaye ni ogun bẹ silẹ ni orilẹ-ede Iraq, to fi mọ bi akoko ti ajakalẹ́ arun asekupani HIV/Aids gbalẹ kan