Ẹ̀kún omi India: Ìsẹ̀lẹ̀ náà ló tíì burú julọ́ làti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn

Awọn ọmọ ilẹ India gun ọkọ ajagbe lati kuro ninu omiyale ni Cochin ni 17 August 2018

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan ni Cochin n lo gbogbo ọkọ ti wọn le ri lati sa kuro nibi ti omiyale wa

Eniyan to ju ọọdurun lọ ti padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ́ ẹkun omi to fa ilẹ riri ni ipinlẹ Kerala to wa ẹkun Guusu India. Iroyin sọ wipe, awọn to tun to ẹgbẹrun lọna ọọdurun miran lo ti di alainile lori bayii lẹyin ojo arọọrọda ni orilẹede naa.

Minisita agba fun Kerala ni omiyale yii lo tii buruju lati bi ọgọrun ọdun ni orilẹede India.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri naa sọ pe, lati igba ti ojo ti bẹrẹ ni India ni oṣu kẹf ọdun 2018, eniyan bii ẹgbẹrun kan lo ti ku.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Awọn oṣiṣẹ pajawiri ni ẹkun Kozhikode fun awọn ara ilu lounjẹ

Akoroyin BBC to wa nibẹ sọ pe, awọn ara ilu ni Cochin ta okun si awọn adugbo ki awọn ti o ba fẹ sa asala fun ẹmi wọn baa ri nkan di mu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ awọn agbalagba ti ko le rin daadaa lo ha sinu omiyale naa.

Awọn ologun naa wa lara awọn to n dola ẹmi awọn ara ilu. Pẹlu ọkọ oju omi ati ọkọ ofurufu ni awọn ologun bọ si igboro lati ran awọn eniyan lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

A gbọ pe Kerala ni odo mọkanlelogoji to n domi sinu okun Arabia, ọgọrin adagun odo to wa leti awọn odo naa lo ti ṣi bayii, nitori pe agbara wọn ko ka awọn odo naa mọ.