Adí-àgbọn: Ọ̀jọ̀gbọ́n Fasiti Harvard ní kẹ má mu àdí-àgbọn mọ́

Adín àgbọn kò dá fún jíjẹ̀- Ọ̀jọ̀gbọ́n Fasiti Harvard Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Májèlé ni àdín àgbọn

Ọ̀jọ̀gbọ̀n kan ní Fasiti Harvard, Karen Michels ní, májelé pọnbélé ni òróró àgbọn ti à mọ sí àdínagbọn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n náà, nígba tó ń fèsì sí fọ́rán ìdínilẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń sọ àwọn àǹfàní tó wà lára òróró àgbọn lórí Youtube.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn èèyàn àti awakọ̀ ké igbe ìrora bí àwọn ọkọ̀ ńlá ṣe dí ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Apapa-Oshodi pa

Bákan náà ni àwọn ẹgbẹ́ àwọn tó ń rí sí ìlera ọkan l'Amerika, rọ̀ àwọn ènìyàn láti yàgò fún àdín àgbọn nínú ìwé ìròyìn Business Insider ti Deutschland.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Karen ni adarí dídènà iṣan wíwú lọ́nà ti kò dára ní Fasiti Freiburg àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Harvard TH Chan nílé ẹ̀kọ́ ilera.

Nínu ìkọ́ni rẹ̀, Michel sàlàyé ìrú òunjẹ tó yẹ kí ènìyàn máà jẹ, tó sì fí kún-un pé àdín àgbọn kò dára rárá fún mimu tabi jijẹ.