Igbe kò sówó làwọn èèyàn mú bọnu lọ́dún Iléyá
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ileya: Àgbò wọ́n torí ọjà ẹran mẹ́ta ni wọ́n tìpa lókè ọya torí Boko Haram

Ninu irinke-rindo BBC Yorùbá, láti mọ bi ọdun Ileya se larinrin si lọdọ awọn ọmọ Naijiria, ọpọ awọn eeyan to ba wa sọrọ ni, ko sowo nita rara, ti ọpọ ẹnu ọbẹ si sélẹ̀ lọdun Ileya yii.

Lawọn ọja gbogbo taa de, awọn ẹlẹran ni ẹran gbowo lori nitori ọja mẹta ni wọn ti pa loke ọya nitori ikọlu Boko Haram.

Bakan naa, lawọn ọlọja ni ọpọ awọn iyawo ile ni ko wa ra oja ọdun nitori pe owo to wa lọwọ idile kọọkan kere si bukata ọrun wọn.

Ọpọ wọn lo wa n rọ ijọba lati mu ki ilu dẹrun fawọn araalu, ki ọdun lee maa rọsọmu fun wọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: