Ìlú Ubang; Níbi tí èdè ọkùnrin ti yàtọ̀ sí t'obìnrin

Ìlú Ubang; Níbi tí èdè ọkùnrin ti yàtọ̀ sí t'obìnrin

Ilu Ubang, jẹ ilu kan ni ẹkun Guusu Naijiria, nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.

Awọn ara ilu naa sọ pe 'ibukun lati ọdọ Ọlọrun'' ni igbe aye aramanda wọn.

Ṣugbọn, bi awọn ọdọ ṣe n fi abule naa silẹ lọ si awọn ilu mii lati ṣiṣẹ, ti ede Gẹẹsi naa si n gbajumọ sii, ti mu ki ijaya wa pe, aṣa naa le parun.

Ohun to ṣokunkun ni pe, ko si ẹni to mọ iye ọrọ ti wọn n sọ ti ko papọ, ko si si aridaju kankan lati sọ boya awọn ọrọ naa wọpọ, tabi boya wọn ni i ṣe pẹlu ojuṣe ti aṣa la kalẹ fun awọn ọkunrin tabi obinrin.

Onimọ kan nipa nkan iṣẹmbaye, to ti ṣewadi ilu naa, Chi Chi Undie, sọ pe àwọn ọrọ kan wa ti ọkunrin ati obinrin jọ n lo, awọn kan si wa to yatọ sira wọn patapata. Bi wọn ṣe n pe e wọn yatọ, wọn ko ni alifabẹẹti kan naa.

Ubang
Àkọlé àwòrán,

Ṣugbọn ohun to daju ni pe, àwọn ọkunrin ati obinrin gbọ ede ara wọn daada, gẹgẹ bi o ṣe ri ni awọn ibo mi i l'agbaye.

Ṣugbọn ohun to daju ni pe, àwọn ọkunrin ati obinrin gbọ ede ara wọn daada, gẹgẹ bi o ṣe ri ni awọn ibo mi i l'agbaye.

Olori ilu naa, Oloye Ibang, ṣalaye pe;eyi ṣeeṣe ko jẹ nitori pe awọn ọmọkunrin n sọ ede obinrin nigba ti wọn n dagba, latari bo ṣe jẹ wi pe ọdọ awọn iya wọn atawọn obinrin mi i ni wọn n gbe ju nigba ti wọn wa ni kekere.

Ipele kan wa ti ọmọkunrin yoo de, ti yoo fi mọ pe oun ko sọ ede to yẹ ki o maa sọ. Ko si si ẹni ti yoo sọ fun ti yoo fi yi ede pada si ti ọkunrin.

To ba ti n sọ ede ọkunrin, awọn to wa ni ayika rẹ yoo mọ pe, o ti balaga.

Ubang
Àkọlé àwòrán,

Ìlú Ubang jẹ́ ìlú tó kún fún àṣà àti ìṣe

Oju ẹni ti ko gbadun ni wọn fi maa n wo ọmọkunrin ti ko ba sọ ede to yẹ nigba to ba ti pe ọjọ ori kan.

Ọwọ yẹpẹrẹ kọ ni awọn ara ilu Ubang fi mu iyatọ to wa ninu ede wọn, wọn si maa n fi iwuri sọ pe awọn yatọ si awọn eniyan to ku.

Ṣugbọn, oriṣiriṣi alaye lo wa lori bi ọrọ ṣe ri bẹ. Ọpọlọpọ ara ilu naa sọ pe o ba Bibeli mu.

''Adamu ati Efa ti Ọlọrun da jẹ ọmọ ilu Ubang,'' oloye naa ṣalaye.

Awọn akẹkọ
Àkọlé àwòrán,

Orí àwọn ọmọ ìlú Ubang kì í wú láti sọ èdè wọn níléèwè

O ni 'erongba Ọlọrun ni lati fun ẹya kọọkan ni ede meji ọtọọtọ, ṣugbọn lẹyin to da ede meji fun awọn ara Ubang , lo to o ye pe ede to wa nilẹ ko le to fun gbogbo eniyan.

Eyi lo si mu ki o dawọ duro. Idi ni yii ti Ubang fi ni ede meji - a yatọ si gbogbo awọn eniyan to wa ninu aye.