'Ògidì ọmọ Yorùbá ni mí, kò sí ọ̀rọ̀ tí n kò lè túmọ̀'

'Ògidì ọmọ Yorùbá ni mí, kò sí ọ̀rọ̀ tí n kò lè túmọ̀'

Èdé Yorùbá jẹ́ àmì ìdánimọ̀ kan fún àwọn ọmọ Yorùbá.

Awọn ọmọ Yoruba tumọ ọ̀rọ̀ 'High Rise Building' èyí to túmọ̀ si ilé gogoro tàbí ilé alá-gbékà ni Yoruba, iyẹn ile to ga, to loke gogoro ti wọn kọ́ si orí ara wọn, to ni àjà tó pọ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lò gbà pé àsìkò ìsinmi yìí dára láti fi kọ́ àwọn ọmọ wa nile síi nípa èdè àti àṣà Yorùbá.

Awọn agba gbàmọ̀ràn pé ọmọ ti a kò kọ́ ni yóò gbe ilé ti a kọ́ tà, fi àsìkò yii kọ wọn sii nípa èdè àti àṣà Yorùbá bii ìbọ̀wọ̀fágbà, ìtẹríba, ìkíni, fífi òótọ́ inú hùwà lawujọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.