Theresa May: A ó fún Nàìjíríà ní £70-million láti pèsè isẹ́

Àkọlé fídíò,

'O yé kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK dán mọ́rán síi lẹ́yìn àbẹ̀wò May'

Ijọba Ilẹ Gẹẹsi ti kede pe awọn yoo fun orilẹ-ede Naijiria ni aadọrin miliọnu owo ilẹ okeere Euros lati fi pese ọkẹ marun isẹ fun awọn ọdọ Naijiria.

Minisita fun ọrọ Ilẹ Afirika ni Ilẹ Gẹẹsi, Harriet Baldwin lo sọ eyi lasiko ti Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Theresa May n se abẹwo si orilẹ-ede Naijiria, gẹgẹ bi ara eto lati se abẹwo si Afirika.

Baldwin sọ pe eniyan miliọnu mẹta lati awọn agbegbe ti iya ati isẹ wa ni orilẹ-ede Naijiria ni wọn yoo mu ibugboro ba igbe aye wọn nipa pi pese ohun amayedẹrun fun awọn eniyan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Theresa May ni ijọba oun yoo fún Nàìjíríà ní £70-million láti pèsè isẹ́

Àkọlé fídíò,

Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Laipe yii, ni Olootu Ilẹ Gẹẹsi naa sọ ni orilẹ-ede South Africa wi pe Naijiria lo ni awọn talaka julọ ni agbaye.

May ní ilẹ Gẹẹsi kò fẹ́ wawọ́ mọ́ ǹkan ìní ọmọ Nàiìjíríà

Olóòtú ìjọba ilé Gẹẹsi,Theresa May,ti seleri lati da owo Nàìjíríà pada sugbọn o le má ya ni kiakia.

Olùrànlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adeshina, lo lede ọrọ yi ninu atẹjade kan to fi sita lori abẹwo May si Aarẹ Muhammadu Buhari ni ile ijọba l'Abuja.

''A ko fẹ wa ọwọ mọ nnkan ìní awọn ọmọ orile-ede Naijiria kankan sugbọn a o ri wi pe a tele ilana to tọ sugbọn o seese ki o pẹ diẹ''

Bakan naa ni Theresa May mẹnu ba pataki kikoju ipenija aabo ati ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti kojú ìpeníjà Boko Haram.

Ninu ọrọ ti rẹ, Aare Muhammadu Buhari so pe oun yoo sa ipa lati ri pe ijọba tarawa fẹsẹ mulẹ lorile-ede Naijiria.

'Digbi ni mo wa lẹyin ki a se idibo to yanranti, inu mi dun pe ẹgbẹ oselu mi n se daadaa''

O tẹsiwaju pe ''Idibo to waye lai pẹ yi ni Katsina Bauchi ati Kogi je oun iwuri fun wa''

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Orilẹ-ede South Africa, Nigeria ati Kenya ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi n bẹwo pẹlu ireti ati tubọ fi idi iṣakoso rẹ mulẹ gẹgẹ bii olootu ijọba

Buhari tun dupẹ lọwọ Thersesa fun ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti kojú ìpeníjà Boko Haram.

Lori ọrọ Brexit, Buhari ni anfaani nla ni eleyi jẹ fun awọn mejeji lati tun tẹsiwaju ninu ajosepo wọn.

Awọn mejeeji tun jiroro lori ọrọ to nii se pẹlu eto ọrọ aje ati eto abo to kan awọn orile-ede mejeeji.

Saaju ni May ti se abẹwo si orile-ede South Africa nibi ti o ti so pe orile-ede Naijiria ni awọn to tosi julo lagbaye.

Theresa May ti tẹsiwaju pẹlu irinajo rẹ lo si orile-ede Kenya.

Naijiria kọ́lo tosi julọ

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni orilẹ-ede Naijiria tẹlẹri, Bolaji Akinyemi ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria kii sọ otitọ nigba gbogbo nipa ọrọ aje Naijiria.

Akinyemi sọ ọrọ yii nigba ti o n fesi si ọrọ ti Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Theresa May sọ lasiko to n se abẹwo si South Africa gẹgẹ bi ara abẹwo rẹ si ilẹ Afrika, pe orilẹ-ede Naijiria lo gba awọn to tosi julọ ni agbaye.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere naa ni awọn ọmọ ilẹ Naijiria kii sọ otitọ nipa iye owo ti wọn n pa nibi isẹ wọn, nitori naa akọsilẹ ti awọn ilu okeere ni nipa Naijiria ko jẹ otitọ lọpọlọpọ igba.

Àkọlé fídíò,

Oriọla: ó yẹ kí a jẹ́ káwọn ọmọ ìsinyi mọ pàtàkì ṣíṣe eré ìdárayá papọ̀

Minisita naa sọ pe igbese to dara ni pe Theresa May n bọ ni Naijiria lati wa se ipade bọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari.

O fikun ọrọ rẹ pe nitori Naijiria jẹ ilẹ ọlọra to ni ohun alumọni ni Ilẹ Gẹẹsi fi n wa ibasepo to dan mọran pẹlu orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti wọn ba kuro ninu Ajọ Isọkan Europe, European Union(EU).

‘Nàìjíríà ló ní akúṣẹ̀ẹ́ tó pọ̀ jùlọ lágbàyé’

Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò gba Theresa May tó jẹ́ olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì níle ìjọba l'Abùja lónìí.

Èrèdí àbẹ̀wò Theresa May sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní láti ṣe àdéhùn lórí ètò kátàkárà tí yóò nípa láàrín Afíríkà àti Brexit.

Bákàn náà ni May yóò jíròrò nípa ètò ààbò, fífí ènìyàn ṣòwò, lẹ́yìn náà ní yóò lọ si Èkó láti sàbẹ̀wò sí àwọn to ti bọ́ sọ́wọ́ ìmúnisìnru lọ́nà ìgbàlódé.

Olóòtú ìjọba náà ti kéde bílíọnu mẹ́rin Pọun láti ran ọrọ̀ àjé ilẹ̀ Afíríka lọ́wọ́

Sùgbọn, bí Nàìjíríà ṣe ń múra sílẹ láti gba Theresa May lálejò ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ké pe ààrẹ Muhammadu Buhari lati ríi dáju pé ó sọ ohun tó tọ àti ọ̀nà ti ìbaṣepọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sí yóò fí ṣe Nàìjíríà láànfàní.

Lóri àtẹ̀jíṣẹ́ twitter, àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ èrò ọkàn wọn fún ilé iṣẹ́ ààrẹ .

Theresa May ti gúnlẹ̀ sí South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Orilẹ-ede South Africa, Nigeria ati Kenya ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi naa yoo maa bẹwo pẹlu ireti ati tubọ fi idi iṣakoso rẹ mulẹ gẹgẹ bii olootu ijọba

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May ti gunlẹ si ilu Cape Town bi o ṣe n bẹrẹ abẹwo rẹ si orilẹede South Africa.

Eyi ni yoo jẹ ibẹẹrẹ abẹwo rẹ akọkọ si ilẹ Afirika nibi ti o ti n reti ati fi idi ajọṣepọ okoowo mulẹ lẹyin ti ilẹ Gẹẹsi ja ara rẹ kuro ninu ajọ ilẹ Yuroopu eleyi ti wọn n pe ni BREXIT.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Orilẹ-ede South Africa, Nigeria ati Kenya ni olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi naa yoo maa bẹwo pẹlu ireti ati tubọ fi idi iṣakoso rẹ mulẹ gẹgẹ bii olootu ijọba.

Ninu atẹjade kan, Theresa May ṣalaye pe, "Bi a ṣe n gbaradi lati fi ajọ ilẹ Yuroopu silẹ, asiko niyi fun ilẹ Gẹẹsi lati tubọ mu ajọṣepọ rẹ pẹlu awọn orilẹede jakejado agbaye gbopọn sii."

"Ilẹ Afirika duro daadaa lati ko ipa to jọju ninu irapada eto ọrọ aje gbogbo agbaye."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

May yoo ṣ'abẹwo si erekuṣu Robben Island nibi ti wọn fi Aarẹ Nelson Mandela si fun ọpọlọpọ ọdun

Lara awọn ibi ti olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May yoo ṣe abẹwo si lorilẹede South Africa ni erekuṣu Robben Island nibi ti wọn fi Aarẹ Nelson Mandela si fun ọpọlọpọ ọdun lati fi ṣami ọgọrun ọdun ti wọn bi Mandela.

Lẹyin eyi ni May yoo tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede Naijiria.