2019 Election: Ẹgbẹ́ ọmọ Nàìjíríà ra fọ́ọ̀mù fún ààrẹ Buhari

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari/twitter

Àkọlé àwòrán,

2019 Election: Ẹgbẹ́ ọmọ Nàìjíríà ra fọ́ọ́smu fún ààrẹ Buhari

Lánà òde yìí ní ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress (APC) gbé owó tí àwọn tó bá nífẹ láti dupò níbi ìdìbò gbogboogbo ọdún 2019 yóò san jade.

Lẹ́yìn eyí ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti ń sọ pé ìgbéṣẹ̀ ẹgbẹ òṣèlú APC kò fí ti mẹ̀kúnù àti t'àwọn ọ̀dọ́ ṣe.

Àkọlé fídíò,

Owó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ gọbọi- olùdíje

Lósàn òní ní àwọn ẹgbẹ́ kan tí wọn pé ara wọn ní ọmọ Nàìjíríà dáradára rá fọ́ọ̀mù fún ààrẹ láti díje lọ́dún 2019 gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bashir/twitter

Àkọlé àwòrán,

Buhar tí gbà fọ́ọ̀mù fún ìdupò ààrẹ ọdún 2019

Gẹ́gẹ́ bí àgbénúsọ fún ààrẹ lóri ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé Bashir Ahmad ṣe sọ lóri àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ pé àwọn ẹgbẹ́ rere ọmọ Nàìjíríà kan ló ra fọ́ọ̀mù náà fún ààrẹ Buhari

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomole ló gba àwọn ẹgbé ọ̀hún sí ilé ẹgbẹ́ lásìkò tí wọn wá ra fọ́ọ̀mù náà lórúkọ ààrẹ

Àwọn ọmọ Nàíjíríà tí bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sì báyìí lóri ríra fọ́ọ̀mu ọ̀hún

Buhari bá àwọn aṣíwáju APC sọ̀rọ̀ lórí ìdìbò 2019

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Buhari lo lewaju ipade naa

Ipade Igbimọ APC waye l'Abuja.

Aarẹ Buhari lo ṣe alaga ipade igbimọ ẹgbẹ oṣelu APC to waye loru ọjọ Iṣẹgun ni ile ijọba nilu Abuja.

Awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC bii gomina ipinlẹ awọn ọmọ ile aṣofin apapọ, awọn minisita atawọn ọtọkulu ẹgbẹ naa lo wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Gomina ana nipinlẹ Eko, Babatunde Faṣọla ati Ambọde n fi ẹrin atayọ ki ara wọn ni gbogbo igba ti ipade naa fi waye.

Pẹlu gbogbo iroyin nnkan o rọgbọ laarin gomina ana nipinlẹ Eko, Babatunde Faṣọla ati gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ to ti n lọ kaakiri fun igba diẹ ẹrin atayọ ni awọn mejeeji fi n ki ara wọn ni gbogbo igba ti ipade naa fi waye.

Oríṣun àwòrán, NAN

Àkọlé àwòrán,

Awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC lo wa nibẹ

Senator Godswill Akpabio ati gomina ana nipinlẹ Delta, Emmanuel Uduaghan ti wọn ṣẹṣẹ fi Ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ APC naa wa nibi ipade naa fun igba akọkọ.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Senator Godswill Akpabio ati gomina ana nipinlẹ Delta, Emmanuel Uduaghan ti wọn ṣẹṣẹ fi Ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ naa wa nibẹ

Eyi si ni irufẹ ipade yii akọkọ ti aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki ko ni si pẹlu bi oun pẹlu ti ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP laipẹ yii.

Oríṣun àwòrán, NAN

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ idibo 2019 ko gbẹyin ninu ijiroro wọn