Ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ṣì dúró lórí ọ̀rọ̀ wọn

Iwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira f'oṣiṣẹ

Àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní Nàìjíríà ti gba Ààrẹ Muhammadu Buhari nímọ̀ràn láti ṣọ̀ra fún ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà Nàìjíríà tí wọ́n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí aṣòdì sí òṣìṣẹ́.

Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé irú àwọn gómìnà yìí ń ṣiṣẹ́ láti da àdéhùn ẹgbẹ́ NLC àti ìjọba àpapọ̀ rú ni lórí 30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Ààrẹ ẹgbẹ́ NLC Ayuba Wabba fọwọ́ sí, wọ́n ní ẹgbẹ́ àwọn gomínà Nàìjíríà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ̀rọ̀ lórúkọ ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan wọ́n sì lọ́ èyí mọ́ alága wọn lẹ́sẹ̀.

NLC, ẹ máa retí ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ 'tórí N30,000

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Ngige àti àwọ́n òṣìṣẹ́

Awọn gomina l'orilẹede Naijiria ti sọ pe awọn ko ni le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun bi bẹẹẹ kọ, ki wọn maa reti idaduro awọn oṣiṣẹ kan lẹnu iṣẹ.

Alaga fẹgbẹ awọn gomina, to tun jẹ gomina ipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari, to ka abọ ipade pajawiri ti awọn gomina naa ṣe l'Ọjọru nilu Abuja, sọ pe ''wọn yoo gbe igbimọ kan dide lati ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ naa.''

Igbimọ naa ni yoo jiroro lati mọ ọna ti awọn gomina le gbe ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ gba, paapa ọgbọn ẹgbẹrun Naira ti wọn n beere fun gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju.

Awọn gomina ọhun sọ pe 'owo oṣu tuntun naa ko le rọrun lati san, ayafi ti wọn ba da awọn oṣiṣẹ kan duro.''

Wọn yan gomina ipinlẹ Eko, Kebbi, Bauchi, Plateau, Akwa-Ibom, Ebonyi, Enugu ati Kaduna gẹgẹ bi ọmọ igbimọ tuntun ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira f'oṣiṣẹ

Igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijria ti sọ wi pe awọn ko tako fifi owo kun owo awọn osisẹ, amọ awọn ko ni owo lati san an ni.

Alaga igbimọ awọn gomina naa to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari fi eyi lede lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ, lẹyin ipade ti wọn se ni ilu Abuja.

Yari ni awọn gomina setan lati se atilẹyin fun fifi owo kun owo osisẹ, amọ ko si owo tabi ohun alumọni ti wọn yoo fi san afikun owo osu naa.

Gomina ipinlẹ Zamfara naa fikun wi pe agbara kaka ni awọn fi n san owo osu awọn osisẹ bayii, ti o si jẹ wi pe iranwọ ijọba apapọ lawọn fi n tiraka lati san owo osu ati ajẹmọnu awọn osisẹ.

Mínísítà fún òṣìṣẹ́ yí ohùn padà lori ifikun owo osisẹ

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù àwọn òṣíṣẹ́ ní àwọn ti fi àdàgbá lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù òṣìṣẹ́ rọ̀ lòdì sí ohun tí Mínísítà Chris Ngige sọ pé ìjọba ò fọwọ́ sí i.

Ìgbìmọ̀ sọ èyí nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn adarí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta ọ̀hún, Comrade Ayuba Wabba, Comrade BAla Bobboi Kaigama àti Comrade Joe Ajaero fọ́wọ́ sí.

Oríṣun àwòrán, Chris Ngige/Facebook, NLC

Àkọlé àwòrán,

Ngige àti àwọ́n òṣìṣẹ́

Wọ́n ní bí Mínísítà ṣe sọ pé ìjọba ṣí ń dúnàá dúrà ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kìí ṣe òtítọ́.Ẹ̀wẹ̀, ìgbìmọ̀ tí ẹgbẹ́ kó jọ yìí sọ pé yéké yéké ni àwọn párí iṣẹ́ àwọn, gbogbo ìgbìmọ̀ fọ́wọ́ sí i láì sí àtakò kànkàn.

Wọ́n ní eléyìí wáyé lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ìgbìmọ̀ tí Sẹ́nétọ̀ Chris Ngige funra rẹ̀ darí tí wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ mẹ́rin yẹ̀wò.

'Ìjọba ò fọwọ́ sí #30,000 fún òṣìṣẹ̀'

Ijọba apapọ ti sọ pe oun ko fọwọ si ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira gẹgẹ bi owo oṣiṣẹ to kere julọ lorilẹede Naijiria eyi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun.

Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati iṣẹ ṣiṣẹ, Chris Ngige lo fọrọ naa lede ni Ọjọru lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari dari rẹ ni Abuja.

Ngige salaye pe ijọba n gbero lati maa san ẹgbẹrun mẹrinlelogun gẹgẹ bi owo oṣiṣẹ to kere julọ, nigba ti awọn ile iṣẹ aladani n gbero mẹrindinlọgbọn.

Àkọlé fídíò,

'Mo kẹ́kọ̀ọ́ fásitì sùgbọ́n aṣọ òké ló ń jáwó báyìí'

Minisita fi kun ọrọ rẹ pe ifọrọwerọ si n lọ lọwọ, ṣugbọn o fidi rẹ mulẹ pe ohun ti o ṣe pataki ju nipe maa fọwọ si owo oṣu ti o ba lagbara lati san.

O ni eyi wa ni ilana pẹlu ofin ti ajọ to n ri si ọrọ oṣiṣẹ lagbaye fi le lelẹ.

Ẹ o ranti pe ẹgbẹ oṣiṣẹ gunle iyanṣẹlodi ninu oṣu kẹsan lati fi ẹhonu han lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lorilẹede Naijiria.

'Aisan owo osu ki se nnkan ti oju ko ri ri'

Gbagbaagba ni wọn ti abawọle ile isẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun pẹlu bi awọ́n osise ti ṣe bẹrẹ iyansẹlodi ikilọ ọlọjọ mẹta.

Iyansẹlodi naa wa ni ibamu pẹlu asẹ ti awọn olori ẹgbẹ osisẹ pa ki awọn osisẹ bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ meta ọhun.

Iroyin to tẹwa lọwọ so pe ko si osisẹ to lo si ibisẹ bi ki sẹ awọn osisẹ alaabo.

Àkọlé fídíò,

Arẹgbẹṣọla: Kò sí ìjọba tí kìí jẹ gbèsè

Bakan naa ni ọmọ sori ni ile isẹ osisẹ ijọba ibilẹ ni Olorunda ati Oṣogbo.

Ọjọ Iṣẹgun ni awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ kede ninu atẹjadẹ kan ki awọn osisẹ yan isẹlodi lataari bi ijọba ti ṣe kuna lati san owó oṣù to le ni osu mẹrinlelọgbọn ati owo oṣu awọn oṣisẹ fẹyinti nipinle naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Famuyantan Razak Olawale

Àkọlé àwòrán,

Aworan iwe ikede Iyansẹlodi ọlọjọ mẹta losun

Ni igba to ń ba ile isẹ BBC Yoruba sọrọ, Komiṣọna fun eto iroyin, Adelani Baderinwa, ni ijọba Gomina Aregbẹsọla n gbiyanju lati yanju aawọ to rọmọ iyanṣelodi naa.

''Bi owo ti se n wa la se n san fun awọn osisẹ.Ki ijọba ati osisẹ jọ joko lati soro lo se pataki.Lati igbati Gomina Aregbesọla ti n se ijọba lati ma'n fi ọrọ jomitoro ọrọ lati yanju ọrọ laarin ara wa.''

Àkọlé fídíò,

Àwọn oṣiṣẹ feyinti ni Osun ṣé iwọde

O salaye pe '' Gomina Arẹgbẹsọla ni erongba lati san gbese ti a jẹ silẹ sugbọn ti a ko ba le san,adehun wa laarin ijọba lati san owo fun awọn osisẹ''

Laipẹ yi ni Ìgboro ìlú Oṣogbo kún fọfọ pẹlú bí awọn oṣiṣẹ feyinti ni ìpínlẹ̀ Osun ti ṣe wọde láti fí ehonu hàn sí bí wọn ti ṣe ní Gómìnà Aregbesola kò sàn owó oṣu awọn.