Kayode Fayemi: Mi ò níi lọ́kàn láti wádìí Fayoṣe

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode fayemi

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ EFCC ni lati wadii Fayoṣe, kii ṣe iṣẹ mi

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ti ni ko si igba tabi akoko kan ti oun sọ fun ẹnikẹni pe ijọba oun yoo ṣewadii Ayọ Fayoṣe.

Ni ọjọ aje ni gomina Fayẹmi sọ ọrọ yii lẹyin to pade ipade idakọnkọ kan pẹlu Aarẹ Buhari ni ile aarẹ nilu Abuja.

Fayẹmi ni ojuṣe awọn ileeṣẹ to n gbogunti iwa ijẹkujẹ niyi ti o si ti wa niwaju wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ohun ti mo sọ ni pe maa ṣe ayẹwo awọn iwe iṣẹ ijọba lati mọ ibi ti iṣẹ de duro nibẹ.

Ojuṣe gomina yoowu to ba ṣẹọ de ipo ni lati yẹ awọn iwe wo. O ni lati mọ awọn ohun to wa nilẹ, gẹgẹ bi mo ṣe ṣẹṣẹ sọrọ nipa agbekalẹ igbimọ olubẹwo si ẹka eto ẹkọ ni ipinlẹ yii."

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

O ni kii ṣe iwadii ni oun fẹ ṣe bi ko ṣe lati mọ ibi ti ijọba to lọ ba iṣẹ de ati ibi ti o ku si.

Kii ṣe ẹjọ mi. Mo fa Fayose le Ọlọrun lọwọ. Mo ti sọ eyi tẹlẹ."

Lọwọ yii, Fayose n jẹjọ ẹsun ikowojẹ ti ajọ EFCC n fi kan an.

Kayode Fayemi: Ọjà ọba tuntun Ekiti kò dára tó la ṣe tìí pa

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Gómìnà tẹ́lẹ̀rí, Ayodele Fayọse ló kọ́ ọjà náà lásìkò tó wà nípò, tó sì ti ta lára àwọn sọ́ọ̀bù fún àwọn ènìyàn.

Gomina ipinlẹ Ekiti sọ pe oun ti ọja tuntun ti wọn kọ si Ado-Ekiti pa nitori wọn kò kọ́ọ daadaa tó.

Fayẹmi sọ eyi ninu atẹjade to fi lede gba ọwọ agbẹnusọ rẹ, Olayinka Oyebọde pe awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn se ayẹwọ Ọja- Ọba naa.

Atẹjade naa fikun un pe awọn ti setan lati da owo pada fun awọn to ti san owo sọọbu ọja naa ko to di wi pe awọn tii pa.

Àkọlé fídíò,

Ògidì ọmọ Yorùbá gbọ́dọ̀ mọ 'áayan ògbufọ̀' dáadàa

Gomina tẹlẹri, Ayodele Fayose lo kọ ọja naa lasiko to wa nipo, to si ti ta lara awọn sọọbu fun awọn eniyan.

Amọ, Agbenuṣọ fun gomina tẹlẹri naa, Ọlalere Ọlayinka lasiko to n fesi si igbese naa, ni awọn faramọ igbese naa sugbọn ijọba gbọdọ ranti adehun ti wọn se pẹlu awọn to ra sọọbu naa, ki wọn to bere igbese lori rẹ.

Ati wi pe awọn ti ọrọ naa kan ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Ekiti ko i tii fi iwe ransẹ si wọn wi pe wọn ti gba sọọbu lọwọ wọn nitori atunse ti wọn fẹ se lori rẹ.

Anfaani maarun un to wa ninu itẹsiwaju isejọba

Orilẹ-ede Naijria lọpọ igba ti koju aisi-itẹsiwaju ninu isejọba kan si omiran, eyi to maa n mu sisan owo osu ati didawọle ohun amayedẹrun lawujọ di ohun pipati.

Awọn gomina ni awọn ipinlẹ kọọkan ni Guusu-Iwọ oorun orilẹ-ede Naijria ko san owo osu ti ijọba to wa nilẹ jẹ silẹ, nitori wọn gbagbọ pe awọn kọ ni wọn jẹ owo osu wọn yii.

  • Ti ijọba kan ba n tẹsiwaju pẹlu awọn ohun ti ijọba tẹlẹ bẹrẹ, ibugbooro a ba isejọba loorekoore.
  • Owo asuwọn fun agbegbe tabi ipinlẹ naa yoo se e lo, lai si wi pe wọn n lo o fun nkan miran nitori wọn ti pa isẹ ti ijọba ti tẹlẹ se ti.
  • Awọn eniyan to n sisẹ fun ijọba naa a jẹ anfaani itẹsiwaju ijọba nitori wọn mọ wi pe isẹ awọn ko ni di ti ẹlomiran ki asiko ifẹyinti awọn to pe.
  • Itẹsiwaju isejọba maa n jẹ kawọn eniyan nigbagbọ ninu ijọba orilẹ-ede wọn, nitori wi pe wọn mọ pe isejọba tuntun ko ni fọwọ yẹperẹ mu ohun ti awọn eniyan se silẹ.
  • Ti ọkan awọn eniyan ba balẹ, ogun ati ija a dikun lawujọ nitori wọn nigbagbọ wi pe ijọba tuntun ko ni fi ẹtọ wọn dun wọn.

Nitori naa ni a ko le koyan isejọba to gbooro kere fun itẹsiwaju agbegbe kan si omiran to fi mọ orilẹ-ede Naijiria.

Ti àwọn to ba gba ipò kò ba tẹsiwaju ninu iṣẹ àkànṣe ìlú, ifasẹyin nla lo maa n jẹ fun ara ìlú.

O yẹ ki itẹsiwaju de ba awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba kò ba pari lain nii fi ṣe bo ya ẹgbẹ oṣelu kan naa ló wọle lẹẹkeji tabi bẹẹ kọ.

Fayẹmi: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àkànṣe tó jẹ́ àsepatì ní màá ṣe yọrí

Gomina tuntun nipinlẹ Ekiti, ọmọwe Kayode Fayẹmi ti ni ipadabọ oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa kii ṣe lati gbẹsan, tabi dẹyẹ si ijọba to kogba wọlẹ.

Fayẹmi ni oun pada wa fun imubọsipo ati itẹsiwaju gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lapapọ.

Fayẹmi fi ọrọ naa lede lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti adajọ agba nipinlẹ Ekiti, Ayodeji Daramọla bura fun un, gẹgẹ bii gomina tuntun ni gbagede Ekiti Parapọ, nilu Ado-Ekiti tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Àkọlé fídíò,

Fayẹmi: Ọ̀pọ̀ èèkàn ìlú ló bá se ayẹyẹ ìbúra

Minisita tẹlẹri ọhun ṣe alaye pe, gbogbo awọn iwe akosilẹ nipa eto ijọba to koja lọ ni oun yoo ṣe afihan rẹ, bẹẹ sini iṣakoso oun yoo rii daju wipe, ipinlẹ naa sun kuro ni ipo to wa lọwọlọwọ bayii.

Àkọlé fídíò,

Ọpẹmipọ Bamgbọpa: Obìnrin gbọdọ̀ kó ara rẹ̀ níjànu lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ nínú tíátà

"Loni, a gba ilẹ wa pada lọwọ awọn to fi wa sinu igbekun. A o ṣe ofintoto, bẹẹ sini a o ṣe afihan akọsile awọn iṣẹlẹ to waye nipinlẹ wa lasiko ijọba to kọja lọ.""Ninu iṣejọba to kọja lọ ni ipinlẹ yii ti jẹ gbese owo oṣu mẹjọ. A ko nifẹ si idajọ lori itakun ayelujara tabi idẹyẹ sini sugbọn o di dandan ki a sọ otitọ ọrọ."

"A ko gbọdo ṣi ilẹkun anfani silẹ fun ẹnikẹni ti ko ni oye iṣejọba lati tọwọ bọ eto oṣelu nipinlẹ Ekiti. Bẹẹ sini a ko gbọdọ ta iyi ti a ni nitori ohun ti a fẹ jẹ."Fayẹmi ṣe alaye wipe lara awọn ifojusun iṣejọba oun ni idagbasoke eto ọgbin, idokowo to muna doko, ipese awọn ohun elo amayedẹrun, idagbasoke eto ọrọ aje ati bẹẹbẹẹ lọ.O tẹsiwaju wi pe, ọpọlọpọ awọn iṣẹ akanṣe to jẹ pipati nipinlẹ naa, ni oun yoo ṣe yọri. Bẹrẹ lati ibi oju ọna ti o ṣee rin, titi ti o fi de ori ibudo igbafẹ Ikọgọsi.

Bakan naa ni o ṣe ileri itọju ti o peye fun awọn arugbo ati ọgọrọ awọn ọdọ ti ko ri'ṣẹ ṣe.O fi kun ọrọ rẹ wipe oun ko ni sinmi titi t'awọn oṣiṣẹ yoo fi ri owo oṣu wọn gba.Fayẹmi dupẹ lọwọ gbọgbọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti nile-loko pẹlu alaye wipe nipasẹ wọn ni anfani lati pada s'ori apere ijọba fi waye.

Kayode Fayẹmi di gómìnà tuntun l'Ekiti

Dokita Kayode Fayemi ti sebura gẹgẹbi gomina tuntun ni ipinlẹ Ekiti.

Fayemi lo jawe olubori ninu idibo si ipo gomina to waye ni Ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹjọ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.

Fidio bi ayẹyẹ ibura naa se lọ lo wa ni isalẹ yii.

Ilu Ado-Ekiti to jẹ Olu-Ilu ipinlẹ Ekiti, ni ayẹyẹ ibura naa ti waye, tawọn gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambọde, Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, Gomina ipinlẹ Ọyo, Abiola Ajimobi ati ti ipinlẹ Kebbi, Atiku Bagudu, si pejọ si ibi ayẹyẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

IVF: Ìyá ìbejì se IVF mẹ́ta lókè òkun, ìkẹrin tó se ní Nàíjíríà, ló fi bímọ

Akọwe ijọba apapọ orilẹ-ede yii, Boss Mustapha, lo soju fun aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari nibi ayẹyẹ naa.

Igbakeji ni yii ti Kayode Fayemi yoo ma tukọ ipinlẹ Ekiti gẹgẹbi gomina. Ọdun 2010 si 2014 ni o ti se saa akọkọ labẹ ẹgbẹ oselu tẹlẹri, Action Congress of Nigeria(ACN).

Lẹyin ti wọn bura tan fun Fayẹmi, lo wa se ayẹwo awọn ọlọpaa to to lọwọọwọ lati yẹ si.

Fayemi ṣe tán láti na tán bí owó pẹ̀lú Eleka n'ílé ẹjọ́

Gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Ekiti, Ogbẹni Kayode Fayemi ti bẹrẹ igbesẹ lati koju oludije ẹgbẹ oselu PDP, Kolapo Olusola Eleka niwaju ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Fayemi /twitter

Àkọlé àwòrán,

Kayode Fayemi ni oludije ẹgbẹ oselu APC to jawe olubori ninu idibo Gomina ipinlẹ Ekiti.

Ninu awijare to fi ẹri to le ni ẹgbẹrun meta segbe re,Fayemi ni oun loun gbegba oroke ninu idibo ọjọ kẹrinla osu keje ọdun 2018 ti o si rọ ile ẹjọ lati ma se ka ẹjọ ti Eleka gbewasiwaju rẹ kun.

Agbẹjọro agba mẹta ati awọn agbejọro miran lo ko sodi lati koju Eleka ti a si gbọ wi pe Hakeem AfoIabi (SAN),Yomi Aliyu (SAN) ati Kayode Olatoke (SAN) wa lara wọn.

Kayode Olatoke (SAN), to gbẹnu sọ fun awọn agbẹjọro to ku ni ofutufẹtẹ ni iwe ehonu ti Eleka gbe wa si iwaju ile ẹjọ ti ko si le so eso rere kankan.

O salaye pe Fayemi fidire janlẹ ni ijọba ibilẹ mejila ninu mẹrindinlogun ti idibo ti waye nipinlẹ Ekiti .

Nigba ti o n fẹsi si ẹsun pẹ iye ibo ti wọn ka ni awn aye idibo kan koja iye awọn to dibo,Olatoke ni aheso ọrọ lasan ni.

Ile ẹjọ ko ti ya ọjọ sọtọ fun igbẹjọ naa