Boko Haram: Ejò lọwọ nínú lórí ikọlù àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà

Awọ̀n ọmọ ikọ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, BBC/Boko Haram

Àkọlé àwòrán,

Awọn Adunkoko mọni Boko Haram sefilọlẹ idunkuku laja wọn lọdun 2009

''Boya o jẹ ootọ tabi irọ, emi ko mọ sugbọn ti o ba jẹ wi pe ikọ Boko Haram n da awọn omoogun Naijiria lọna ti wọn si n seku pawọn,ọrọ yi fe amojuto ni kiakia''

Esi ọrọ ti ajagunfẹyinti nigba kan,ọgagun Ayo Olaniyan sọ fun ileesẹ BBC Yoruba rẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan nipa ọrọ ikọlu awọn omoogun orileede Naijiria ti Boko Haram pa to aadọta ninu wọn.

Ile ise ologun Naijiria ti ni ko si ootọ ninu iroyin naa sugbọn ọpọ ile ise iroyin lo gbe iroyin naa jade pe awọn ikọ Boko Haram lo sigun ba awọn ọmọ ogun Naijiria ni agbegbe Sari ni ipinlẹ Borno.

Ayo Olaniyan to fi igba kan jẹ oludari ni ẹka to n risi ọrọ iroyin ni ileese ologun Naijiria so pe oun to bani lọkan jẹ ni ki a ma gbo iroyin pe awọn Boko Haram n sigun ba awọn ọmọ ogun Naijiria

'''Ti iru nnkan bayi ba n selẹ, ko si nnkan to tọka si to ju wi pe awọn kan n fun awọn agbesunmọmi yi ni iroyin nipa isesi awọn ọlogun wa ni.''

Olaniyan tẹsiwaju pe ''aibikita si iwadi to gunrege ati otẹlẹmuyẹ lo sokunfa bi awọn Boko Haram ti se n le koju awọn ọmọ ogun Naijiria''

''Awa lo yẹ ki a ni iroyin ati ọtẹlẹmuyẹ nipa Boko Haram,kii se awọn''

Àkọlé àwòrán,

Bi ikọ Boko Haram se n se ikọlu rẹ losoosu

Iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà ní irọ́ ni ìròyìn tó jáde síta l'ọ́jọ́ kíní oṣù Kẹsàn án, pé ikọ̀ Boko Haram pa ọgbọ̀n ọmọ ogun.

Agbẹnusọ fún ikọ̀ Operation Lafiya Dole, Ọ̀gágun Onyeama Nwachukwu ní lóòtọ́ ní àwọn ọmọ ogun àti ikọ̀ Boko Haram d'ojú ìjà kọ ara wọn, tí àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun Boko Haram, tí wọ́n sì tún rí àwọn nkan ìjagun wọn kó.

Nwachukwu ni òun kò tí rí i gbọ́ pé ọmọ ogun Nàìjíríà kankan kú níbi ìjà nàá. Àti pé kò tọ́ fún ẹnikẹ́ni láti maa sọ pé àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ tó bẹ̀ẹ̀ ni àwọn pàdánù.

Ṣáàjú ni ìròyìn kan látí iléèṣẹ́ ìròyìn AFP gbé e pé àwọn ọmọ ikọ̀ Boko Haram ṣekú pa ọgbọ̀n ọmọ ogun Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Borno.

Àkọlé àwòrán,

Ikọlu Boko Haram lọdun 2016

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ AFP, alẹ́ Ọjọ́bọ̀ ni àwọn ọmọ ogun Boko Haram ya bo ibùdó àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà ní abúlé Sari, ìpílẹ̀ Borno, tí wọ́n sì gba ìṣàkóso agbègbè nàá fún ìgbà díẹ̀.

Ọmọ ogun kan tó bá ikọ̀ ìròyìn AFP sọ̀rọ̀, ní ''wọ́n ya bo ibùdó iléèṣẹ́ ọmọ ogun nàá, tí wọ́n sì jọ kojú ara wọn fún bi i wákàtí kan.''

''Ó ní wọ́n borí àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà, wọ́n sì tún kó àwọn nkan ìjà kó.''

Àti pé àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà nàá ṣe bi i akọni pẹ̀lú bí wan ṣe fi bàálù kojú Boko Haram, kí wan tó na pápá bora.''

Ṣùgbọ́n, iléèṣẹ́ ológun kò sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí ìjà nàá ṣe wáyé. Wọ́n kàn kéde rẹ̀ lójú òpó Twitter wọn ni pé ''àwọn ọmọ ogun dojú ìjà kọ Boko Haram ní Sari.''

Ko si alaye kankan lori iye ọmọ ogun to ku ninu isẹlẹ naa. Wọn kò sí ṣàlàyé kankan lórí iye ọmọ ogun tó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ nàá.

Ìwádìí atọpinpin BBC fihàn pé iks agbésùnmọ̀mí Boko Haram,rán ènìyàn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá s'ọ́run ní ọdún 2017. Èyí ló tí ì pọ̀jù láti ìgbà tí wan ti n ṣọṣẹ́.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ilu Maiduguri lorilẹede Nigeria ni ibudo afojusun Boko Haram julọ

Awọn wo gan la n pe ni Boko Haram?

Ikọ adunkoko mọni ni Boko Haram, to si kọlu ijọba orilẹede Naijiria lọdun 2009 pẹlu erongba lati se agbekalẹ isejọba ẹlẹsin Islam lagbegbe iwọ oorun Afrika.

Ikọ naa, to dojukọ ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, lo ti ran eeyan bii ọkẹ kan (20,000) sọrun ọsangangan, to si tun ti sọ awọn eeyan bii miliọnu meji di alaini ile lori.

Boko Haram, ti Abubakar Shekau n dari rẹ, lo ti jẹjẹ atilẹyin rẹ fun ikọ tamọ ntiye ISIS losu kẹta ọdun 2015. Amọ nigba to di osu kẹjọ ọdun 2016, ni ikọ Boko Haram fọ si wẹwẹ, lẹyin ti ikọ IS kede pe wọn ti rọ Shekau loye.

Afikun nba ikọlu wọn sugbọn ibudo afojusun wọn ko yatọ.

Iroyin ni, apapọ ikọlu ti Boko Haram se jẹ aadọjọ (150) lọdun 2017, eyi si fihan pe ọwọ ikọ adunkoko mọni naa mulẹ pupọ lọdun 2017 ju tọdun 2016 lọ, nitori ikọlu mẹtadinlaadoje (127) lo se lọdun 2016.

Ni ọdun mejeeji yi, osu kinni ọdun ni ikọlu Boko Haram peleke julọ, ti ọwọja wọn si rinlẹ pupọ eyiun lẹyin ti aarẹ Muhammadu Buhari ti ni oun ti ri opin ikọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Bi ikọ Boko Haram se n se ikọlu rẹ losoosu

Awọn ibudo ti Boko Haram n kọlu ko yatọ lati ọdun meji sẹyin.

Orilẹede Naijiria si lo faragba ọpọ ikọlu naa julọ lọdun 2016 ati 2017, ti ipinlẹ Borno si jẹ ilu abinibi awọn adunkoko mọni ọhun, ti wọn n dojukọ julọ.

Bakanaa ni ikọ Boko Haram fidi rẹ mulẹ pe oun lee tun gba ilẹ kan si lọdun 2017 pẹlu bo se tun kọlu ẹknu ariwa orilẹede Cameroon, agbegbe Niger Diffa ati Lake Chad, ti gbogbo wọn wa leti aala ilẹ ila oorun ariwa Naijiria.

Aworan yi se afihan awọn ibudo ti Boko Haram yan mu lati kọlu lọdun 2016, amọ iyatọ diẹdiẹ wa laarin ọdun meejeeji, ti orilẹede Naijiria si ni iriri ikọlu to pọ julọ lọdun 2017, ti orilẹede Niger si ni ikọlu Boko Haram to kere julọ lọdun naa.

Àkọlé àwòrán,

Aworan agbegbe ti Boko Haram kọ̀lu julọ̀ lọ̀dun 2016

Àkọlé àwòrán,

Awọn agbegbe ti Boko Haram kọlu Lọdun 2017

Ọna ti Boko Haram maa ngba se ikọlu rẹ.

Iroyin ni, ikọlu aadọrun (90) ni awọn gende agbebọn se nigbati ikọlu awọn aso ado iku mọra jẹ mọkandinlọgọta (59).

Orilẹede Naijiria naa si ni ori ikọlu wọnyi ta julọ, ti ikọlu Boko Haram to buru julọ si jẹ tawọn agbebọn.

Ni aala ilẹ Naijiria si Cameroon, ikọ naa nsamulo ilana to yatọ, ti wọn si nlo awọn aso ado iku mọra ju awọn agbebọn lọ.

Bakanaa ni wọn lo ilana yi lawọn orilẹede mejeeji lọdun 2016.