OsunDecides: Saraki ní kò sí ìpínlẹ̀ tó jẹ òsìsẹ́ lówó tó Ọ̀sun

Aarẹ ile igbimọ aṣofin Bukọla Saraki nibi ipolongo ibo ni Osun
Àkọlé àwòrán,

Saraki ni inira ati awọn ipenija to n ba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun finra ko lẹgbẹ lorilẹede Naijiria

Aarẹ ile igbimọ aṣofin Bukọla Saraki ni ko yẹ ki itẹsiwaju de ba ẹgbẹ tabi ijọba ti ko ṣe anfani fun awọn eeyan ilu.

Saraki sọ ọrọ ọhun l'Ọjọru nibi aṣekagba ipolongo ibo to waye ni gbagede 'Freedom Park' ilu Oṣogbo fun oludije si ipo gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnatọ Ademọla Adeleke.

O tẹsiwaju wipe bi orilẹede Naijiria ba nilo atunṣe lootọ, lati ipinlẹ Ọṣun gan lo ti yẹ ki awọn oludibo fi apẹrẹ rẹ han lọjọ kejilelogun oṣu kẹẹsan ọdun yii.

Saraki fi kun ọrọ rẹ wipe, inira ati awọn ipenija to n ba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun finra ko lẹgbẹ lorilẹede Naijiria, pẹlu alaye wipe ko si ipinlẹ to jẹ awọn oṣiṣẹ lowo to ipinlẹ Ọṣun lati igba ti iṣejọba awarawa ti bẹrẹ lọdun 1999.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni

"Igba to ku bii ọsẹ kan si idibo ni wọn wa san diẹ lara owo yin. Ẹyin eeyan mi l'Ọsun, wọn ko fẹran yin o. Ẹ jẹ ki wọn mọ wipe iru ẹ ko gbọdọ ṣẹlẹ mọ l'Ọṣun

Mo ti ṣe gomina ri fun ọdun mẹjọ, bakan naa sini mo ti jẹ alaga igbimọ awọn gomina. Lati igba ti. ti bẹrẹ iṣejọba awarawa lọdun 1999, mi o mọ ipinlẹ kankan ti wọn ti jẹ gbese owo oṣu fun ọdun mẹta gbako yatọ si ti ipinlẹ Ọṣun.

Wọn si ni ki ẹ dibo yin fun itẹsiwaju.

Njẹ a le pe ijọba to n jẹ gbese ni onitẹsiwaju?"

Saraki tẹsiwaju wipe jakejado orilẹede Naijiria ni awọn gomina ti n wa ojutu si ọrọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ, titi to fi de awọn apa ibi ti Boko Haram ti n ṣoro bi agbọn, sugbọn bakan naa kọ lọmọ ṣori nipinlẹ Ọṣun.

O rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati tuyaya jade lọjọ kejilelogun oṣu kẹẹsan ọdun yii, ki wọn si fi ibo wọn le ijọba ajigbese kuro ni ipinlẹ Ọṣun.

Àkọlé àwòrán,

Ogunlọgọ awọn eeyan to ti de sibi ipolongo ibo naa ni wọn wọ asọ ẹgbẹjọda ti wọn tẹ́ẹ ami idamọ ẹgbẹ oselu PDP si lara.

Lara awọn eekan to bawọn peju-pesẹ sibi aṣekagba ipolongo ibo naa ni igbakeji aare orilẹese yi tẹlẹri, Atiku Abubakar, aare ile igbimọ asofin tẹlẹri, David Mark.

Awọn yoku ni, alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu PDP, ọmọọba Uche Secondus, gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed, gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Ọtunba Gbenga Daniel ati bẹẹbẹẹ lọ.

Gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si 'Davido' naa ko gbẹyin nibi ipolongo ibo fun aburo baba rẹ, Ademọla Adeleke ti o jẹ oludije si ipo gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Eto idibo si ipo gomina ipinlẹ Ọṣun yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu kẹẹsan ọdun yii, Ademọla Adeleke yoo si maa takangbọn pẹlu awọn oludije mẹtadinlaadọta mii.

Bi o tile jẹ wipe aago mejila ni wọn sọ wipe eto naa yoo gbinaya, titi di aago meji ọsani, nnkan ko tii fi bẹẹ ṣarajọ nitori awọn alejo pataki ti wọn n reti ko tii gunlẹ si papa ipolongo.

Ogunlọgọ awọn eeyan to ti de sibi ipolongo ibo naa ni wọn wọ asọ ẹgbẹjọda ti wọn tẹ́ẹ ami idamọ ẹgbẹ oselu PDP si lara.

Àkọlé àwòrán,

Oorun mu, ti oju ọjọ si dara laisi ifarahan ojo wẹli-wẹli kankan to lee ba eto ipolongo ibo naa jẹ.

Oorun mu, ti oju ọjọ si dara laisi ifarahan ojo wẹli-wẹli kankan to lee ba eto ipolongo ibo naa jẹ.

APC pàdánù aṣòfin míràn ní'pínlẹ̀ Osun

Ninu iroyin miran ẹwẹ, Pẹlu gbogbo gbọnmọgbọnmọ iroyin nipa awọn oloṣelu to n fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ nipinlẹ Ọsun, kaka ki ewe agbọn ọ dẹ fun ẹgbẹ oṣelu naa, lile lo n le ṣii o.Nibayii, ọmọ ile asofin ipinlẹ Ọṣun miran tun ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Dokita Olaolu Oyeniran to n ṣoju fun ẹkun idibo Odo-ọtin nipinlẹ Ọsun ti gbera sọ lọ si ẹgbẹ oṣelu ADC.Ọmọlẹyin gomina ana nipinlẹ Ọsun, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla to tun jẹ agba ọjẹ lẹgbẹ oṣelu ADC ni ọpọ eeyan mọ aṣofin Oyeniran si.Ilu Okuku ni aṣofin Oyeniran ti kede pe ohun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADC eyi ti ko tii pe wakati merinlelogun ti awọn aṣofin mẹta kan ti kọkọ kede awọn n fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ nipinlẹ ọhún.

Aṣòfin mẹ́ta míràn fi APC sílẹ̀ lọ darapọ mọ́ ADP

Nnkan ko fẹ ṣe deede fún ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọsun lọwọ yii pẹlu bi awọn ọmọ ileegbimo aṣofin ipinlẹ naa mẹta tun ti ṣe yẹba lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADP ni ọjọ abameta.Bi ẹ ko bá kúkú ní gbàgbé, ẹgbẹ ADP yii kan naa ni Alaaji Moshood Adeoti tó jẹ akọwe ijọba labẹ ijọba gomina Rauf Aregbesola to jẹ ti ẹgbẹ APC darapọ mọ lẹyin to kuro laipẹ yìí.Ẹni tó n baa dije gẹgẹ bii igbakeji, iyẹn ọjọgbọn Durotoye Adeolu gan an lo tẹwọ gbà awọn aṣofin mẹta yii.

Awọn aṣofin to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ naa ni:

  • Họnọrebu Debo Akanbi ti o n ṣoju ẹkun idibo Ariwa Ẹdẹ, (Ede North)
  • Họnọrebu Tajudeen Famuyide to n ṣoju ẹkun idibo iwọ oorun iléṣà (Ilesha west) ati
  • Họnọrebu Abdullahi Ibrahim ti ẹkun Iwo.

Ninu ọrọ to ba awọn ololufẹ rẹ sọ nibẹ, Họnọrebu Debọ Akanbi ṣalaye wí pé, " A mọ ipilẹṣẹ APC nipinlẹ Ọsun, a si ni adehun pẹlu gomina Arẹgbẹṣọla lati lo ọdun mẹjọ rẹ nipo, kii ṣe lati wa yan eeyan kan le wa lọwọ nigba ti o ba ṣetan ati lọ.

"A ko faramọ jijoye baba isalẹ le ẹgbẹ lori, mi ṣi n fi daa yin loju pe púpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo ṣi n bọ"

Oríṣun àwòrán, @MoshoodAdeoti

Àkọlé àwòrán,

Adeoti wa lara awọn ọmọ ẹgbẹto kọkọ fi ẹgbẹ oselu APC silẹ nipinlẹ Osun .

Ẹ kọwe fí ipò silẹ

Bi ẹ ko ba ní gbagbe kò tíì pé ọsẹ meji ti aṣofin Clement Akanni to n ṣoju ẹkun idibo Ila to jẹ agbegbe ọkan lara awọn àgba ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹ ede Naijiria, oloye Bisi Akande, pẹlu ti dagbere fun ẹgbẹ oṣelu naa to sì gba ẹgbẹ oṣelu PDP lọ.Amọṣa o, ẹgbẹ oṣelu APC ti ni igbesẹ awọn aṣofin mẹta yii ko tu irun kan lara oun o.Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ Ọṣun, Amofin Oyatomi sọọ ninu atẹjade kan to fi sita lori ikanni WhatsApp awọn oniroyin nipinlẹ Ọsun pe arọwa ọmọluabi ti ẹgbẹ APC fẹ gba awọn aṣofin naa ni pe ki wọn kọwe fi ipo ti wọn wa gẹgẹ bíi aṣofin silẹ nitori aya ọlẹ laa gba, ẹni kan kii gba ọmọ ọlẹ.