Ìbúgbàmù Somalia: Àwọn ọmọ ilé ìwé farapa nínú ìbúgbàmù

Awọn eeyan n dorika ibi ti isẹlẹ naa ti gbemi eeyan mẹta

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Obinrin kan n sa kuro nibi ti ibugbamu ti waye ni Mogadishu

Eeyan kan to wa ọkọ ti o ko ado oloro si inu rẹ ti se okunfa ibugbamu kan to se akoba fun ile isẹ ijọba kan ni olu ilu Somalia, Mogadishu ti o si tun ko ipalara ba ile iwe kan to sunmọ ibi iṣẹlẹ naa.

Ado oloro to bu gbamu ni agbegbe Howladag ni awọn osisẹ ijọba lagbegbe naa sọ fun BBC pe o se iku pa ọmọ ogun mẹta ti eeyan mẹrinla si farapa.

Ọmọde mẹfa wa ninu awọn to farapa ọhun.

Awọn ile to wa ni tosi isẹlẹ naa to fi mọ mọsalasi kan la gbọ pe ibugbamu naa ko ba.

Ikọ ọmọ ogun Al Shabab ti o wa nidi igbesunmọmi lagbegbe yii ti ni isẹ ọwọ awọn ni.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@abdi_adaani

Àkọlé àwòrán,

Agbesunmọmi to wa nidi ibugbamu naa wa ọkọ to gbe ado oloro wọ inu ọgba oun ni

Salah Hassan Omar to jẹ osisẹ ijọba lagbegbe naa sọ pe awọn ọmọ ogun mẹta to ku ko agbako nigba ti wọn dina mọ ki agbesunmọ naa ma gbe ọkọ to fẹ fi se isẹ ibi naa wọnu ọgba ile isẹ ijoba kan.

Raqiya Mahamed Ali, ti oun naa wa ninu ọgba naa nigba isẹlẹ oun ni ''ẹnu isẹ wa la wa ki a to saa dede gbọ ibugbamu naa''

O sọ fun ile isẹ iroyin Reuters pe ''Mo sa asala fun ẹmi mi si abẹ tabili. Ni se ni iro ibọn gbalẹ... nigba ti ngo fi jade sita,se ni mo ri ọpọ eeyan to farapa nilẹ ti awọn miran si ti ku''

Lai ọdun 1991 ni orileede Somalia ti n koju ipenija rukerudo ati iwa janduku lati igba ti awọn kan gba ij ba lọwọ awọn ologun.