Ìjọba àpapọ̀ buwọ́lu $1.3b fún àkanṣe iṣẹ́ márùn ún

Reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

'Buhari yoo si tẹsiwaju lati pari awọn apati akanṣe iṣẹ gbogbo dipo bibẹrẹ awọn miran'

Ijọba apapọ ti buwọlu owo to le ni biliọnu kan dọla owo ilẹ Amẹrika fun nina lori awọn akanṣe iṣẹ to loorin kan.

Gẹgẹ bi minisita feto iroyin, Alaaji Lai Mohammed ṣe sọ ọ lasiko to fi n kopa lori eto ileeṣẹ Mohunmaworan apapọ Naijiria, NTA, inu òṣuwọn ajọni fun idokoowo, Sovereign Investment Fund ni wọn ti fa owo naa yọ lati fi yanju akanṣe iṣẹ marun kan kaakiri ibu ati oro orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn akanṣe iṣẹ ti ọrọ kan ni opopona marosẹ Eko si Ibadan, afara keji ori odo Niger pẹlu opopo alasopọ ẹkun ila oorun si iwọ oorun orilẹede Naijiria.

Awọn akanṣe iṣẹ miran ti ọrọ kan tun ni opopona marosẹ Abuja si Kano pẹlu akanṣe iṣẹ lori ipese ina ọba lati Mambilla.

Minisita Lai Mohammed ni iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari ti fara rẹ jin fun idagbasoke ohun amayedẹrun gbogbo jakejado orilẹede Naijiria; yoo si tẹsiwaju lati pari awọn apati akanṣe iṣẹ gbogbo dipo bibẹrẹ awọn miran.

Àkọlé fídíò,

'Wiwa ọkọ Baalu da bi ki ẹ lọ da duro sori apata'