Ìdìbò 2019: Ọmọ ẹgbẹ́ APC àti PDP fìja pẹ́ẹ́tà l'Ábuja

Atiku nílé ẹgbẹ PDP

Oríṣun àwòrán, Atiku/twitter

Àkọlé àwòrán,

Ijà bẹ́sílẹ̀ nílé 'ẹgbẹ́ PDP

Ija bẹ silẹ lolu ile iṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Abuja loni Ọjọbọ lẹyin ti igbakekeji Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri Atiku Abubakar lọ fi fọọmi idije fun 'po ààrẹ sọwọ sile ẹgbẹ pada.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress àti àwọn ọmọ ẹgbk òṣèlú People's Democractic Party PDP ló fìjà pẹ́ẹta ní kété ti ààrẹ àná Atiku Abubakar ṣe àdá pada fọọmù ìfèróngbà rẹ̀ hàn láti du ipò ààrẹ lọ́dún 2019

Oríṣun àwòrán, Atiku/twitter

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP fìja pẹ́ẹ́tà nílé ẹgbẹ PDP l'Ábuja

Rúkèrúdò òhún tó wáyé fún ǹkan bi ọgbọn iṣéjú tí fi àpá málagbàgbé sí àwọn obìnrin méjì kan nígbà ti wọn ń gbìyànjú láti wọ olú ilé ẹgbẹ́ PDP.

Bí elòmíràn ṣé ń lèkò ní àwọn míràn ń yọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Vanguard ṣe sọ pé ìjà bk sílẹ̀ nígbà ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC dà ps mọ àwọn PDP pẹ̀lú àsìá ẹgbk wọn lọ́wọ́.

Ìròyìn fí kúu pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pe ọ̀kan níja pé kí ló wá ṣe ní àgbo àwọn, èyí ló dí ariwo tí wọn sì fìjà pẹ́ẹ́ta tí ẹníkan sí lu alátìlẹ́yìn Atiku lálùbami.

Tajutaju l'awọn ọlọpaa fi pẹtu saawọ naa nibi ti awọn eeyan kan ti farapa

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ atunto eto iṣejọba jẹ ohun ti o ti gba iwaju ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria

Ọkan lara awọn oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni Alhaji Abubakar Atiku; o si ti bẹrẹ ifikuluku kaakiri orilẹede Naijiria lori ilepa rẹ.

Lopin ọsẹ to kọja ni Alhaji Atiku gbe ifikuluku rẹ de ọdọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre to jẹ ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba, Oloye Ayọ Adebanjọ nibiti iroyin ti sọ pe Oloye Adebanjọ kan sara sii pe eeyan ti awọn lee fi ọwọ rẹ sọya pe yoo ṣe ifẹ awọn Yoruba nitori ipe rẹ fun atunto eto iṣejọba lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ atunto eto iṣejọba jẹ ohun ti o ti gba iwaju ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria, amọṣa ọpọ ni ko mọ boya Alhaji Atiku ti lewaju ipe yii tabi rara.

Alhaji Abubakar Atiku ti wa lara awọn to lewaju ipe fun atunto ilana iṣejọba lorilẹede naijiria lati igba ti iṣejọba to wa lode bayii ti gun ori aleefa.

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ Naijiria ti n sọrọ lori abẹwo yii ati boya Atiku lee ṣika adehun rẹ lori atunto ilana iṣejọba

Diẹ lara awọn asiko ti o ti sọrọ lori rẹ niyii:

  • Nibi idanilẹkọ kan to pe ni 'Ṣiṣe atunto fun iṣọkan Naijiria', lọdun 2016 Atiku sọrọ nipa pataki atunto ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria.
  • Ni ọjọ Kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2018 ni Alaaji Atiku Abubakar kede pe bi oun ba lee di aarẹ orilẹede Naijiria, oṣu mẹfa pere ni yoo gba oun lati ṣe atunto ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria ni ibi eto kan ni Chatham House ni ilẹ Gẹẹsi.
  • Ni bi ọrọ to sọ ni oṣu keji ọdun 2018 nibi ifilọlẹ iwe kan ti ọgbẹni Tọla Adeniyi kọ nilu Eko, o ni 'atunto ilana iṣejọba ko lee tan gbogbo iṣoro Najiria ṣugbọn yoo ran an lọwọ lati yanju pupọ ninu rẹ.'
  • Bakan naa lasiko to ṣabẹwo si gomina ipinlẹ ipinlẹ Bayelsa ni oṣu kẹfa ọdun 2018 ni oun ti 'n lepa atunto ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria lati ọdun 2004.'
  • Ni oṣu keje ọdun 2017 ni Atiku pe Saraki atawọn sẹnetọ ẹgbẹ oṣelu APC nigba naa ni ọdalẹ atunto ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria 'pẹlu bi wọn ṣe kuna lati gba aba lori pinpin agbara ẹka iṣejọba gbogbo.'
  • Ni ọpọ igba ni Alaaji Atiku ti sọ ọ gbangban-gbangba lori ikanni twitter ati facebook rẹ pe gbáá-gbá-gbá loun wa fun atunto eto ati ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria.
  • laipẹ yii ni Atiku tun da igbakeji aarẹ lohun pe ọrọ rẹ kudiẹ kaato lori ilana eto iṣejọba lorilẹede Naijiria.

Amọṣa awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n sọrọ lori abẹwo yii ati boya Atiku lee ṣika adehun rẹ lori atunto ilana iṣejọba bi o ba ni anfani lati de ori aga aarẹ.