Sẹnẹtọ David Mark ṣèlérí láti yí Nàìjíríà padà láàrin ọdún méjì

David Mark

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

David Mark fìfẹ́ hàn láti dupò ààrẹ

Ààrẹ ilé ìgbìmọ àṣofin tẹ́lẹ̀ rí David Alechenu Bonaventure Mark so pe ọdun meji loun yoo fi se atunto orileede Naijiria ti wọn ba yan oun sipo Aarẹ.

O lede ọrọ yi nigba ti o lọ gba ìwé ìfèrongbà han lolu ile ise ẹgbẹ oselu PDP labuja ní ìgbáradì lati du ipo Aarẹ ninu ìdìbò gbogboogbo ti ọdún 2019.

Gẹgẹ bi oun ti a ri gbọ lati ọdọ ile isẹ iroyin Sahara Reporters,Mark ni iwe ilana oun to n jẹ '730' da lori atunto Naijiria.

O si ni laarin ọdun meji loun yoo se atunto yi.

''Mo ti n se oselu bọ ọjọ ti pẹ,O da mi loju pe mo le mu iyipada to munadoko ba Naijiria ti gbogbo ọmọ orileede yi yoo si jẹri si''

Saaju ni Mark ti kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ labẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) .

Àtẹjáde to gba ọwọ́ olúdari ètò ojule dé ojúlé fun David Mark James Oche sọ pé ọ̀gá òun lẹ́yin tó fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbààgba jákèjádò Nàìjíríà ló gbé ero rẹ̀ sita láti díje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

David Mark ní òun fẹ́ díje lati gba orílẹ̀-èdè yìí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìṣùbú ni.

Ní báyìí Bukola Saraki, Rabiu Musa Kwankwaso, Atiku Abubakar, Ahmed Markarfi, Aminu Tambuwal àti David Mark ló ti fi èrongba wọn han lati dí ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.