INEC 2019: Kí ló leè mú INEC fẹ́ sún ìdìbò síwájú?

awọn agunbanirọ nibudo idibo kan
Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari kọ lati buwọlu atunyẹwo abadofin ọdún 2018 fun eto idibo to mbọ nitori awọn ohun to pe ni 'kudiẹ kudiẹ' kan to wa ninu rẹ

Iroyin ti bọ sigboro pe o ṣeeṣe ki ajọ INEC o sun idibo ọdun 2019 siwaju nitori awọn ohun to n ṣẹlẹ lagbo eto abo.

Iroyin yii ba ọpọlọpọ ni àbo nitori pupọ awọn onwoye eto oṣelu ni wọn ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako bii PDP ni wọn ti koro oju si iroyin ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa o, ajọ eleto idibo, INEC ti bọ sigboro lati pariwo sita pe ko si ohun to jọ bẹẹ ninu eto wọn.

Ajọ naa ni erongba awọn kan ti wọn fẹran lati maa ko imi ẹṣin da sile ẹran niyii.

Ṣe idi wa fun awọn onwoye lati bẹẹru?

Ṣe awọn agba bọ wọn ni o nbọ, o mbọ, awọn laa dẹ dee; eyi gan an lo fa ti ọpọ fi n ko aya soke lori iroyin yii.

Àkọlé fídíò,

Arẹgbẹṣọla: Kò sí ìjọba tí kìí jẹ gbèsè

Bi a ko ba si ni gbagbe, bayii naa ni ọrọ ṣe bẹrẹ ni ọdun 2015 lasiko ti iroyin fi kọkọ jade pe ajọ INEC nigba naa yoo sun idibo aarẹ siwaju eleyii ti alaga ajọ shun nigba naa, Ọjọgbọn Atahiru Jega ti sọ pe ko si oun ti o jọ

Ẹyin-o-rẹyin ni ajọ naa pada wa kede ayipada ọjọ idibo naa.

Abala kẹrindinlọgbọn ti ajọ naa sa di lọdun 2015 ni ọfiisi alaga ajọ naa bayii, ọjọgbọn Mahmood Yakubu sọ pe o mẹnu ba lasiko ipade pẹlu awọn adari ẹka eto abo fun eto idibo ni Naijiria.

Ṣugbọn ninu ọrọ kan to ba BBC Yoruba sọ, kọmiṣọna agba fun eto ipolongo ati idanilẹkọ faraalu, Ọmọọba Deji Ṣoyebi ni gbogbo nnkan lo ti to fun idibo lajọ naa.

Àkọlé àwòrán,

Ajọ INEC ni ko si idi fun ayipada idibo

Ohun miran to tun n kọ ọpọ lominu ni awuyewuye to n waye lori bibu ọwọ lu aba eto idibo tuntun eleyi ti aarẹ kọ lati buwọlu.

Iwoye ọpọ ni pe ṣe eyi naa ko ni fi aaye awawi silẹ fun sisun idibo siwaju?

Amọṣa kọmiṣọna agba fajọ INEC, Deji Ṣoyebi tun jẹ ko di mimọ pe gẹgẹ bii ajọ to n tẹle ilana ofin, iwe ofin idibo to wa nilẹ tẹlẹ to jẹ ti ọdun 2010 eleyi ti wọn n lo titi di asiko yii naa ni ajọ naa yoo maa lo titi digba ti ọrọ ba yanju lori abadofin eto idibo tuntun naa.

Niwọn igba ti ajọ yii ti fi da araalu loju, ireti awọn oludibo orilẹede Naijiria ninu ileri ati idaniloju rẹ pe ko ni si ayipada ninu ọjọ idibo apapọ 2019 ṣi duro lai yẹ.

Ṣé ó ṣeéṣe kí INEC sún ìdìbò 2019 síwájú?

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán,

Ṣé ó ṣeéṣe kí INEC sún ìdìbò 2019 síwájú?

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti ni ko si idi fun oun lati sun idibo 2019 siwaju o.

Ajọ INEC ṣalaye ọrọ yii ninu atẹjade kan ti o jade lati ọfiisi alaga ajọ naa, ọjọgbọn Mahmood Yakubu

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

INEC ni awọn eeyan kan lo gba ọrọ lẹnu alaga ajọ naa sọ pe o salaye nibi ipade awọn ẹṣọ alaabo lori idibo Naijiria, ati pe ami to n foju han bayi lee mu ki ajọ naa sun idibo siwaju

Ajọ INEC ti ni irọ patpata ni iroyin naa.

O ni oun ti alaga ajọ naa ṣe lalaye fawọn adari ileeṣẹ alaabo gbogbo nibi ipade atigbadegba ti wọn maa nṣe lori eto abo fun idibo ni pe o yẹ ki igbims naa tubọ tẹmpẹlẹ mọ ipade rẹ nitori eto idibo apapọ ọdun 2019 ti n sunmọ'le.

Oríṣun àwòrán, InEC

Àkọlé àwòrán,

INEC ni awọn eeyan kan lo gba ọrọ lẹnu alaga ajọ naa sọ pe o n gbaa lero lati sun idibo ọdun 2019 siwaju

Alaga ajọ INEC ṣalaye fun igbimọ aabo naa pe, "ko si bi idibo ṣe lee waye laarin rukerudo. O si tọka si abala kẹrindinlọgbọn iwe ofin idibo lorilẹede Naijiria to fun ajọ naa laṣẹ lati sun idibo siwaju 'bi idi ba wa fun un lati gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wahala waye bi wọn ba tẹ siwaju pẹlu idibo naa ni ọjs ti wọn da fun un tabi nitori ajalu kan tabi pajawiri."

Bakan naa lo ni alaga ajọ INEC tun lo anfani ipade naa lati pe akiyesi awọn ileeṣẹ alaabo naa si awọn fidio kan to n kaakiri ninu eyi ti awọn oloṣelu kan ti n sọrọ to le dabu eto abo ṣaaju, lasiko tabi lẹyin idibo lọdun 2019.

O ni nitori naa ko si ibi ti alaga ajọ naa tabi ajọ INEC lapapọ ti gbaa lero lati sun idibo ọdun 2019 siwaju.

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari kọ lati buwọlu atunyẹwo abadofin ọdún 2018 fun eto idibo to mbọ nitori awọn ohun to pe ni 'kudiẹ kudiẹ' kan to wa ninu rẹ

INEC ní kíkùnà ààrẹ láti buwọ́lu òfin ìdìbò kò dí ìbò Ọ̀ṣun, 2019 lọ́wọ́

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti sọ pe kikuna ti aarẹ kuna lati buwọlu iwe aba atunyẹwo ofin eto idibo orilẹede Naijiria ti ọdun 2018 ko lee di igbesẹ ati igbaradi ajọ naa fun awọn idibo ọjọ iwaju, paapaa eto idibo gomina nipinlẹ Ọṣun ati eto idibo apapọ lọwọ.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Ọmọọba Deji Shonubi to jẹ ọga agba fun eto ipolongo ati ilanilọyẹ fawọn oludibo lajọ INEC lorilẹede Naijiria ni ofin to ba wa nilẹ ni ajọ INEC ma n tẹlẹ fun ilana iṣẹ rẹ gbogbo ati pe ko lee si idiwọ bi o ti wulẹ ko mọ fun ajọ naa lati gbaradi fun awọn idibo to n bọ lọnakaakiri orilẹede Naijiria.

Àkọlé àwòrán,

Ajọ INEC ni ko si idi fun ayipada idibo

Ọmọọba Shonubi ni ki agbado to daye kini kan ladiyẹ n jẹ lawọn n fi ọrọ naa ṣe nitori naa ofin eto idibo kan wa nilẹ tẹlẹtẹlẹ eleyi ti ajọ naa n lo ṣaaju agbekalẹ iwe aba atunyẹwo ofin eto idibo orilẹede Naijiria ti ọdun 2018 ti a n sọrọ rẹ yii.

"Laarin aarẹ ati awọn aṣofin ni ọrọ yii wa ti ko si fi bẹẹ fi gbogbo ara kan ajọ INEC eleyi ko si lee di igbaradi fun idibo ipinlẹ Ọṣun atawọn igbesẹ eto idibo fun ọdun 2019 lọwọ rara nitori sẹpẹ la wa lakọ bi ibọn."

Àkọlé àwòrán,

Ajọ INEC sọ pe kikuna aarẹ lati buwọlu iwe aba atunyẹwo ofin eto idibo ọdun 2018 ko lee di igbesẹ ati igbaradi ajọ naa lọwọ

Lori ọrọ igbaradi fun idibo sipo gomina nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Shonubi to tun jẹ Kọmiṣọna agba ajọ INEC to n ṣe amojuto ẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria ni eto idibo sipo gomina nipinlẹ Ọṣun yoo tun dara ju ti ipinlẹ Ekiti to waye loṣu keje ọdun yii lọ nitori ajọ naa ti ṣe awọn atunṣe to yẹ sawọn kudiẹ0-kudiẹ to fi oju han nipinlẹ Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

PDP ni awọn awawi ti aarẹ n tọka si ko lee fi ohunkohun tayọ pataki atunṣe aba idibo naa

Ìdí tí Buhari fi wọ́gilé àtúnṣe àbá ètò ìdìbò

Aarẹ Muhammadu Buhari kọ lati buwọlu atunyẹwo abadofin ọdún 2018 fun eto idibo to mbọ nitori awọn ohun to pe ni 'kudiẹ kudiẹ' kan to wa ninu rẹ.

Olubadamọran fun aarẹ Buhari lori awọn ọrọ gbogbo to jẹ mọ ile aṣofin apapọ, Sẹnetọ Ita Enang ni aiṣe atunṣe gbogbo to yẹ lori abadofin naa nitori awọn agbeyẹwo ati atunṣe iṣaaju to ti waye lori rẹ lo fa awọn 'kudiẹ kudiẹ' ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sẹnetọ Enang ni aarẹ ti fi ọrọ naa to awọn aṣofin ile mejeeji nile aṣofin apapọ leti ṣaaju.

"Aarẹ ti ke sawọn aṣofin apapọ lati tete wa nnkan ṣe si 'kudiẹ kudiẹ to farahan naa ki oun lee tete buwọlu lu u.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Sẹnetọ Enang ni aarẹ ti fi ọrọ naa to awọn aṣofin ile mejeeji nile aṣofin apapọ leti ṣaaju

O ni lara awọn kudiẹ kudiẹ ti a n sọrọ rẹ ọhun ni ti wahala aito ọjọ fun ajọ INEC lati ko orukọ awọn oludije pọ ati paapaa julọ ṣe akoso idibo abẹnu awọn ẹgbẹ oṣelu mọkanlelaadọrun to wa nilẹ bayii.

O ṣalaye pe atunyẹwo abadofin naa ko gbe abala kọkanlelọgbọn, ikẹrinlelọgbọn ati ikarundinlaadọrun to mojuto akoko fifi orukọ awọn to nifẹ lati dije ṣọwọ si ajọ naa, gbigbe orukọ awọn oludije sita to fi mọ ipolongo akoko idibo ẹgbẹ ati fifi orukọ awọn oludije ti wọn mu han yẹwo.

Kini awọn ẹgbẹ alatako n sọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari ni oun ko lee buwọlu iwe atunyẹwo abadofin eto idibo ọdun 2018 nitori awọn ohun to pe ni 'kudiẹ kudiẹ' to wa ninu rẹ

Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke sawọn aṣofin apapọ lati wọgile igbesẹ aarẹ Buhari naa nipa agbara ti ofin gbe le wọn lọwọ.

Ninu atẹjade kan eleyi ti alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria, Kọla Ologbondiyan fi sita, ohun ti aarẹ ṣe lori abadofin naa ko jẹ iyalẹnu nitori gẹgẹ bii ọrọ rẹ, "aarẹ ko figbakan tẹlẹ naa fi ara rẹ jin fun eto idibo ti ko ni ẹja n bakan ninu."

O ni awọn awawi bi wọn ṣe tẹẹ ati awọn aṣiṣẹ ti aarẹ n tọka si ko lee fi ohunkohun tayọ pataki atunṣe aba idibo naa fun igbeleke idibo to tọna, to jọju ti o si jẹ ojulowo ni ọdun 2019.