Ìdìbò 2019: kò s'ọ̀dọ́ tó lè ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ní #45m

Àkọlé fídíò,

Owó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ gọbọi- olùdíje

Olùdíje fún ipò aṣojú-ṣòfin àgbà l'Abuja Kolawole Temitope to fẹ soju ẹka idibo Okitipupa-Irele nipinlẹ Ondo sọ pé #45m owo rira fọọmu fun awọn oludije fun ipo rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti pọju.

Temitope to ba BBC Yoruba sọrọ fidi rẹ mulẹ pe ọgbọn a ti dena awọn ọdọ lati dije ninu idibo aarẹ ọdun 2019 ni ẹgbẹ APC n da lo jẹ ki wọn gbowo gọbọi le fọọmu naa.

Temitope sọ pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ naa ti ni awọn ti wọn fẹ ki wọn dije lọkan ki wọn to kede owo naa.

O ni kosi ọdọ kankan to le ri iru bayii lati ra fọọmu idije fun ipo kan tabi omiran.

Ninu atẹjade kan ti igbimọ amusese ẹgbẹ naa fi sọwọ si awọn oniroyin,wọn kede ilana ti ẹgbẹ yoo lu lati sk idibo abẹnu fun idibo gbogbogbo ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, @APC Nigeria

Oríṣun àwòrán, @APC Nigeria

Lọjọ kaarun osu kẹsan ti se ọjọru ni wọn yoo bẹrẹ sini ta ìwé ìfèrongbà han ti ipade gbogbogbo ẹgbẹ yoo waye ni ọjọ kejila osu kẹsan.

Gbogbo awọn oludije fun ipo Aarẹ,Gomina asoju ile asofin agba ati ile asoju sofin yoo gba fọọmu wọn ni olu ile ise ẹgbẹ to wa ni Abuja.